Yoruba Lesson Note for SS2 Second Term

Lesson note on Yoruba for SS2 Second Term – Edudelight.com

SECOND TERM ILAANA ISE NI SAA KINNI FUN SS2

YORUBA LANGUAGE

OSEAKORI EKO
1EDE – Aroko (Leta gbefe) Awon eto ati ilana leta gbefeAdiresi ikini, deeti, koko oro, asokagba ati bee bee lo ASA – Isinku ni ile Yoruba I Orisirisi bii iku se n pani apeere, aisan, ijamba lorisirisi, afomowofe ati bee bee loItufo ati itoju oku ni ile YorubaIbanikedun ati sise oku agba LITIRESO – Asayan iwe litireso ti ajo WAEC/NECO yan ti egbe akomolede ipinle Eko fi owo si
2EDE – Aayan ogbufo Titumo ayolo ewi ni ede geesi si ede YorubaAwon offin to ro mo aayan ogbufo ASA – Isinku ni ile Yoruba II Orisirisi oku ati bi a se n sin wonOku omode (b) Oku obinrin (d) Awon oku abamiOku riro ati etutu oku sise bi ti elegun ba ku, won gbodo se etutu fun un ki eegun si jade lojo naa LITIRESO – Itupale lori iwe Litireso ti ajo WAEC/NECO yan fun SS2 Awon eda itanIbudo itan
3EDE – Aayan ogbufo oloro wuuru: Titumo eyo oto gbolohun ede geesi si ojulowo ede YorubaTitumo ayolo ipin afo lati ede geesi si ede Yoruba ASA – Eto ogun jije I Itumo ogun ati ohun ti an je logunIyato laarin ogun iya ati babaOna ti a n gba pin ogun ni ile YorubaAwon ti o ni eto si ogun pinpinAleebu to rom o ogun pinpin LITIRESO – Itupale iwe litireso: Ahunpo itan ati asa Yoruba to suyo ninu itan naa
4EDE – Aroko (leta aigbagbefe) Igbese leta aigbagbefeAdiresi, deeti, ikini, akole, koko oro, ikaadi, oruko ati ifowosi ASA – Eto ogun pinpin II Ipa ti ofin ijoba n ko lori ogun laye ode oni LITIRESO – Sise itupale asayan iwe litireso: Awon ilo ede lakanlo edeSise orinkinniwin won
5EDE – Iparoje ati isunki: Pipa iroje ibi ti ipaje yii ti le waye apola oruko apola ise ati awon ihun miiran ASA – Eto idajo laye atijo: Ona ti a fi n se idajo laye atijo beere lati odo oba, baale ati ijoyeIpa ti emese / ilari n ko ninu eto idajo LITIRESO – Kika iwe asayan ti ajo WAEC/NECO yan
6EDE – Aranmo: Itumo aranmoOrisii aranmoOfin to ro mo aranmo ASA – Eto idajo lode oni: Idajo lode oni ni ile ejo orisirisi, ile ejo ibile, ile ejo giga, ile ejo kotemilorun, ile ejo togajulo igbimo, eleti gbaroye ati beebee loIpa ti olopaa ati woda n ko ninu idajo ode oniIse agbejoro ninu idajo odeoniEto yiyanju aawo lori redio ati telifison LITIRESO – Kika sayan iwe litereso Yoruba ti ijoba yan
7EDE – Oro agbaso: Afo asafoAfo agba oroAwon wunren ti maa n lo ninu oro agbaso ASA – Aroko pipa: Orisirisi awon n kan ti a fin paroko ati itumo wonIdi/anfani ti a fin paroko ni ile Yoruba LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan
8EDE – Oro/gbolohun onipoona: Itumo poonaAkojopo awon oro onipoonaAlaye lori itumo oro ati gbolohun onipoona ASA – Eewo ni ile Yoruba: Kini eewo/orisi eewoOrisirisi eewo ati itumo okankan wonKi ni o maa n sele ti eniyan ba deja eewo ati atunbo tan re LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan
9.EDE – Awe gbolohun ede Yoruba: Oriki ati alaye kikun lori awe gbolohunOrisi awe gbolohunOlori awe gbolohunAwe gbolohun afarehen ASA – Igbagbo ati ero Yoruba nipa Ajinde leyin iku LITIRESO – Awon eka ede Yoruba: Ohun ti eka ede jeAwon eka ede to wan i ipinle kookan
10EDE – Apola ninu gbolohun ede Yoruba: Apola orukoApole iseIhun apolaAwon isori oro ti a le ba pade labe apola oruko ati apola ise ASA – Igbagbo Yoruba nipa Olodumare: Tani Olodumare?Awon oruko ti Yoruba fi n pe OlodumareAbuda ti awon Yoruba fi n pe Olodumare LITIRESO – Kika iwe ti ijoba yan
11Atunyewo lori gbogbo ise saa yii
12&13Idanwo ipari saa yii

OSE KINNI

AKORI EKO: LETA GBEFE KIKO Leta kiko Ni  ona ti a n gba paroko ero inueni ni ori pepa ranse si elomiran

Leta gbefe ni leta ti a maa n ko si awon to ba sunmo wa pekipeki. Iru leta yii fi aye gba ohunkohun to ba wu wa lati so fun idi eyi oun tun ni a n pen i leta orosore. Awon ti a maa n ko o sin i baba, iya, aburo, egbon, iyawo, oko, aunti ati beebee lo.

ILANA KIKO LETA GBEFE

Adiresi – eyi ni adiresi ako leta maa n wa loke otun iwe wa.nomba ojule opona tabi apoti ifiwe ranse ,oruko ilu ati deeti gbodo wa ni abe adiresi.

Ikinni ibere – eyi ni ilana bi a se n ki eni ti a n ko leta si. Apeere: Egbon mi tooto, Aburo mi owon, Aya mi owon, Ore mi toto, Ololufe mi owon, Baba mi tooto ati beebee lo. Iru eni ti a ba n ko leta sin i yo so iru bi a o se ki eni bee

Ifaara – eyi ni bi a o se so oro – akoso ki a to lo si koko leta. Eyi naa farajo ikini.

Koko leta – Eyi ni ibi ti koko ti a fi ko leta yoo fi han. Idi pataki ti a fi ko leta maa n han ni inu koko leta.

Ipari leta – Eyi ni aye ti a fi maa n pari leta kiko wa. Bi apeere: Emi ni ore re tooto Sade.

Ewe oruko akoleta nikan ni o gbodo han ni ipari leta.

AWORAN LETA GBEFE

                                                                                    Adiresi Akoleta

Ikinni

Ifaara

Aarin leta

Ikadii

Ipari leta

Lesson note on Yoruba for SS2 Second Term – Edudelight.com

OSE KEJI

AKORI EKO: ASA ISINKU NILE YORUBA

Isinku je eye ikeyin ti a n se fun oku lati dagbere fun kuro lori ile aye Yoruba gbagbe pe gbese ni iku je fun gbogbo eda alaye, sugbon won maa n gbadura pe ki eniyan dagba ki o si dogbo ki o to dagbere fun aye. Igbese isinku yato lati ilu tabi eya kan si omiiran. Paapaa julo ona ti a n gba sinku arugbo tabi odo yato si bi a se n sinku alaboyun, afin, eni ti o pokunsi, eni ti o ku sinu odo abule abbl.

IGBESE ISINKU

1. ITUFO: Eyi ni kikede fun gbogbo ebi ibatan o re, ojulumo alaabagbe pe ‘lagbaja ti fi ile se aso bora’. Eyi tunje ona ti a fin n so di mi mo fun awon eniyan pe enikan ti dagbere fun aye. An se eyi lan le se ipalemo sisnku eni ti oku ati lati le fun awon omo, ebi, ore ati ojulumo ni aaye lati wa ati kopa ninu eto isinku.

2. OKU WIWE: A maa n se eyi lati toju oku nipa fifi kan-in-kan-in ati ose we fun oku, rire ekannaa oku, gige tabi didi irun ori won, fifi atike ati lofinda oloorun didun kun ara won leyin eyi, won yoo wo aso oke tabi funfun pelu gele tabi fila fun won.

3. ILE OKU GBIGBE: Ni awujo awon Yoruba awon ara oku ni won maa n gbe saa re oku. Ni aye atijo mo ayika ile oku ni won maa n sun oku si.

4. OKU TITE: Eyi ni sise afihan oku fun igba ikeyin lati je ki awon omo ebi ore, ara ati ojulumo ki won losoo. Awon eniyan yoo maa woni okookan won yio si yipo re.

5. ALEJO SISE: Awon omo ati ebi oku yoo pese jije, mimu fun awon okunrin ilea won ti won gbele oku ati awon alejo won gbogbo.

6. ISINKU: Eyi ni ayeye fifi erupe fun erupe, won yio gbe oku sinu posi pelu oniruru nkan bi eko funfun, obi abata, aso, bata opaitile, ileke ati oniruru ajo re, won yoo fi owo eyo kan, won yoo gbe adiye tele koto, bi won ba ti gbe sinku koto awon omo olooku ati yio bu erupe.

7. OKU SISE: Leyin ifo-dogun (15 days) awon iyawo oku yoo bere opo sise fun odindin osu meta gbako, won koni fi oju kan ita. Aso dudu ni won yio ma wo, leyin osu keta won yoo se aye ye ijade – oko won yoo si bere si ma wo aso to ba wu won.

8. OPO SISU: Awon ebi oko ti won n ye okunrin yio mu awon iyawo oku ti won ba si wan i omo bi aya. Eyi ni a ma n pe ni won su won lopo.

OSE KETA

AKORI EKO: ETO ENI SI OGUN JIJE

Ogun ni ile Yoruba je ohun elege nitori pe opolopo ohun ibi ni o ti rom o ogun pinpin laarin awon eniyan ti won je ebi kan maa paapaa julo laarin omo iya si omo iya.

Ni apakan ile Yoruba won kii pi n ogun fun awon omobinrin ninu ebi nitori won gbagbo pe gbogbo ohun ini ti obinrin ba ni bi ogun  ini ti oko re ni, nitori eyi omokunrin nikan ni won maa n pin ogun fun, idi nipe “Arole” ni won maa n pe omokunrin (won kii ni oruko baba won pada, awon sini eni ti o maa n mu obinrin wa si inu ile won lati inu ebi, ilu tabi eya miiran.

Ogun baa ni agbe elege julo, paapaa ti okunrin naa ba je oniyawo meji tabi ju bee lo. Idi igi ni won maa pin ogun naa si eyi da lori iye iyawo ti okunrin naa ban i kii se ni pa iye omo ti obi. Idi igi koo kan duro fun iya kookan ibaa sepe omo kan soso o ni iyawo kan.

Baba isinku (olori ebi) ni o maa n se ko kaa ri gbogbo bi eto isinku ati ogun pinpin yio seje nitori oun ti eni ti oku fun rara re yan ni gba aye re a ti se eyi n oun ko ohun ti o bas i so ni gbogbo mole bi gbogbo ti yipada imo ijinle si tun lesiwaju aaye wa fun enikeni  lati seto ile re sile ki olojo to de sinu iwe akosile ti a n pen i “will” ti o si le se atunse ni oore koore ki o to to akoko, okan yoo wan i owo agbejoro ekeji ni owo ijoba (kootu agba) eketa yoo si wan i owo eni ti oko. Eyi ni won tio ka ni ile ejo le yin osu mefa tabi odun kan leyin iku ologbe si eti gbogbo molebi omo ati nja wo oku.

OSE KERIN

AKORI EKO: AROKO KIKO (LETA AIGBAGBEFE / AIGBEFE)

Eyi ni leta ti a ko si awon eniyan ti won wan i ipo kan ni ibi ise adaani tabi si ajo ilu. Leta bayii kii se si enikan pato, eniti o je oga ni asiko naa le kaa. Idi niyi ti a kii fi ko oruko eniyan kan si.

Ninu leta aigbagbefe, ko si aaye fun iroyin tabi efe rara. Apeere irufe leta yii ni n ko si Ajete, Olotuu iwe iroyin, Giwa ile-ise, Oba, Alaga igbimo, Alaga ijoba ibile, oga ile – iwe ati akowe agba ibi ise ijoba apapo bii oga agba ajo idanwi WAEC, NECO ati JAMB.

 Igbese Leta aigbagbefe

a. Adiresi: Adiresi meji nil eta aigbafe maa n ni

i. Adiresi akoleta: eyi yoo wa ni owo otun oke iwe, deeti ojo ti a koi we yoo tele ni isale.

ii. Adiresi agbaleta: Eyi yoo wan i owo osi ni ila ti o tele deeti. Apeere:

                                                                                    Federal Government College,

                                                                                    Ilorin,

                                                                                    Kwara State.

                                                                                    2nd February, 2015.

Olotuu,

Iwe Iroyin Alaroye

34, Agbabiaka Street,

Lagos.

b. Ikini Ibeere: Apa osi ni ila ta tele adiresi agbaleta ni akoleta yoo ko ikini akoko si leta n la ni o gbodo fi bere yoo si fi ami koma kadii re. apeere:

                                    Olotuu,

                                    Oga ile – iwe,

                                    Akowe agba, abbl

d. Akole leta aigbefe: Ila ti o tele ila ikini ni akoleta yoo ko akole leta re si ni aarin iwe yoo si fara sidii re ti o ba ti leta kekere ko o tabi ki o ko o nil eta nla lai fala si nidii. Apeere:

            Ayeye Ojo Omiran Orile – Ede Naijiria.

e. Ara leta: Aaye ko si fun iforo jewoo tabi awada ninu leta yii, ohun ti a ba fe so ni pato ni a gbodo gbe kale. Ti o ba si je esi iwe ti akoleta ko gba tele tabi ko ni a gbodo fihan.

e. Ikadii/ipari: owo otun ni isale iwe ni akoleta yoo ko igunle leta re si, oruko meji (iyen ni oruko akoleta ati obi re) ni o gbodo ko pelu ami idanuduro ni ipari. Apeere:

                                                                                                Emi ni,

                                                                                                Biodun Agbabiaka.

                                                                                                (signature)

Ise Asetilewa

Ko leta si oluko agba ile – iwe re, ki o so awon idi ti o fi ni le wa si ile – iwe lola.

OSE KARUN- UN

AKORI EKO: ORAN DIDA ATI IJIYA TI O TO

Laye atijo ko si ofin ti a ko sile gege bi ti ode – oni. Sugbon, a no awon asa, eewo, ilana ti awon agba fi n se eto agbo ile ati akoso ilu. Bi o tile je pe ako ni akosile ofin naa gege bi a ti nii ninu iwe ofin lode oni, ole jija, ipaniyan, alonilowogba, ifipa – jale, ati iwa buburu gbogbo ti a n tun ri lode oni, ko to bee po rara.

Eto idajo lori esun odaran lode oni ati ti aye atijo ko fi bee yato rara, gbogbo igbese bi ki agbo tie nu ti a fi esun kan a o si fun un laye lati pe eleri ti yoo ferii gbee leyin naa, a o se iwadi esun naa fin-ni-fin-ni. Ti o ba jare, a o daa sile ki o maa lo ni alaafia. Sugbon ti o ba jebi, a o fii ijayi ti o to jee. Bi ese bat i n pon to ni ijiya se nto.

Awon ohun ti eniyan le se ki a to so pe o daran pupo ni wonyii:

  1. Ipaniyan
  2. Fifi ipa ba obinrin lo
  3. Fifi dukia jona
  4. Agbere sise
  5. Idife si ilu eni tabi si ijoba
  6. Ole jija
  7. Ifipa jale
  8. Idigun jale
  9. Jiji omo gbe
  10. Sise afojudi si awon Oba, Ijoye ati awon alase ilu
  11. Biba nkan ajumolo je laini idi
  12. Ona dida
  13. Sise ogunika
  14. Lilo agbara aye lati se aidaa
  15. Fayawo ati kika oogun oloro wolu

Lesson note on Yoruba for SS2 Second Term – Edudelight.com

OSE KEFA

AKORI EKO: EEWO ILE YORUBA

Ohun aimo (eyi ni ohun ti ko to, ohun ti ko wo, ohun ti ko ye) ti a ko gbodo se. Awon ohun ti asa esin ati ise wa ko gba laa ye lati se ni a n pe ni eewo. Yoruba bo won ni “eni ti o ba se ohun ti enikan o se ri, oju re a ri ohun ti enikan ko ri ri”.

Awon Yoruba kii fe dejaa eewo nitori won mo wipe eja a maa hun ni tabi fa ki ohun buburu sele si onitohun. Nigba miiran ohun buburu ti a lero le ma sele, sugbon ohun ti o se pataki ni eko ti won fe ko ni.

Bi eewo se wa fun agba, bee naa ni o wa fun omode ni ile Yoruba, eewo agbalagba lejo mo eewo esin ibile tabi ti molebi (idile) bee eewo awon ewe/omode wa lati ko omo lekooni ibamu pelu bi ironu ati ojo ori won se mo patakijulo, eewo je ona kan gbogi ti ori mu ki igbe aye alaafia ati ife joba ninu awon Yoruba.

ORISIRISI EEWO ILE YORUBA

1. EEWO FUN IMOTOTO TABI OFIN ILERA

EEWOOHUN TI YIO SELEIDI TI O FI DI EEWO
a. A ko gbodo fo aso ni aleIya eni naa yio kuKi aba le reran ri bi aso naa na mo tabi ko mo
b. Ako gbodo to sinu odoBi eni naa ko ba mu omi aro yo kuO le je odo ti won mu o si le fa aisan fun opolopo eniyan
d. A ko gbodo jokoo ni enu ona jeunEni naa ko ni yoPanti le gbon si ounje naa bi awon eniyan se n lo ati bo
e. A ko gbodo je irun oriEni naa yio kuIrun ori le doti o si le fa aarun si ago ara
e. A kii ji te epo egusi moleO sin i yio ta eni naa pa X440x16Ki a le maa gba ile wa leyin ti a ba se egusi tan
f. A kii fi igi owo danaEni naa yoo kuLati dekun awon eni ti n fi igi owo sina tabi sere
g. A ko gbodo fi owo gbe ojoOwo eni naa yio maa gbonLati dekun fifi owo ko idoti ati otutu
gb. A ko gbodo fi ese te eyin tabi edo inu ibepe mo leEni naa yio ya aroKi a le maa ko eyin ibepe ati eso inu re danu nitori o le yon i subu

2. EEWO FUN ITONI (AKONILOGBON): Awon eewo ti o wa labe isori yii je eyi ti o le toni sona ti on aba daru tabi lati ko ni lekoo sise lodi si iru awon eewo bayii maa n mu ijiya kan tabi omiran lowo. Apeere:

EEWOOHUN TI YIO SELEIDI TI O FI DI EEWO
a. A ko gbodo fo ile agbonAwo ti eni naa ba n gbe, yio ma foAgbon le ta eniyan loju
b. Omode ko gbodo fi igi fa ila sileIya omo naa yio kuKi igi naa ma ba gun ni ikun tabi oju
d. A ko gbodo fi igbale naa omokunrinIkan omokurin re yio kuO le wo oju ara re lo
e. Omode ko gbodo mo obi re loju tabi naa obi reOsi yio ta omo naa paIwa aito ni
e. Omo iya kannaa ko gbodo ba obirin kan lo poBi won ba see sit i igbonwon gba ara won nidii ounje eyi rgbon yio kuLati dekun iwa aito
f. A ko gbodo naa alaboyunKi omo ti yio bi ma ban i apa daraKi a ma aba fi owo gba ni kun

3. EEWO FUN IGBEAYE ALAAFIA: Awon eewo yii wa fun imu larale ati igbe aye irorun. Apeere:

EEWOOHUN TI YIO SELEIDI TI O FI DI EEWO
a. A ko gbodo ru idi igi gba arin tabi agbi ile kojeEniyan kan yio ku ninu ile naaLati dekun ijamba fun awon ewe ti n sare kiri
b. Okunrin ko gbodo fe obinrin tie se re koni koje gbinBi o ba fi esegbe ipanti wole, ile naa yoo di ahoroLati dekun iku ninu idele/ile
d. Aboyun kogbodo dakun dele sunOmo inu re le ku tabi ki o yaroOyun le tibe baje lara re
e. Aboyun ko gbodo rin ni aru tabi ninu oorun osan ganganAnjonu le le omo inu re jade ki osi wonu re loLati dekun irin oru tabi osan fun won le ni ki won ta okuta mora
e. Omo ko gbodo jabo leyin iya reBi o ba je obinrin, okunrin meta yio kun i ori re, bee gege ni okunrin naaKo awon abiyami maa mojuto awon omo won daradara
f. A kii rorin aleOko tabi aya eni ti oba dan-an wo yoo kunO le seeriejun eni ti o ba n sare bo ninu okunkun

4. EEWO IDILE: Inui tan orirun tabi oriki orile Yoruba ni opo eewo idile ti n suyo. Eewo idile le wa fun iyawo tabi omo – ile. Okookan eewo yii wa ye nitori iwa aidara ti won hu si eru-binrin nigba asiko isoro omo bibi

Idile / iran ati eewo

  1. Olu – oje ——- won kii je eye ega
  2. Onikoyi ——– won ko gbodo je okete
  3. Idile miiran obinrin to sese bimo ko gbodo je iyo

Ise Asetilewa

Ko awon ohuneewo laarin awon elesin wonyii:

  1. Oya
  2. Esu
  3. Sango
  4. Elesin musulumi
  5. Elesin onigbagbo

Lesson note on Yoruba for SS2 Second Term – Edudelight.com

OSE KEJE

AKORI EKO: ORO ONAPON – NA

Pon – na ni ki oro tabi ifo niju itumo kan lo. Ti a ba fi oye oro awon oro tabi apola inu ede Yoruba finnifini an ri wipe awon oro kan wa ti won maa n ju itumo kan lo. Won le je eyo oro – oruko, oro – ise tabi akanlo – ede ti a dalo ninu gbolohun. Bi apeere:

1. Tinu – tinu leje oruko bi apeere: Tinuade, Tinuola

Tinu – tun le tumo si ankan inu eran bi edo

2. Odi – Mo ri odi kan laa naa

Odi – le tumo si eni to ko gboro

(fence) odi le tumo si ogiri ti a mo yii ilu ka

Odi – (boarder) o le tumo si enu ona ilu

3. Ayo (name) Ayo Kosi nibe

Ayo (joy) Ayo ko si ninu ila naa

4. Gun – o ti gun ri nnkan maa kuni

Gun – ki ewure sese ni oyun

5. Mobuta – mo jeun

Ki a fi owo bu ata si inu nnkan kan

6. Obawaja: Oba ilu kan

Oba ilumo inu orule ile

7. Mojuba ehoro – mo sare tele

Mo fi owo fun ehoro

8. Iya eye naa tide – igba to bi iya aje

Iya ti o je aje gan-an lode

9. Ija aje naa ti de yato bi iya aje

Iya ti oje aye gan-an lode

10. Omo Akin – Omo ti Akin bi

Akinkanju omo

Omo ise Akin

11. Bola ti wo ileya – o ti dagba oti to pa eran odun ileya

Bolu ti to loko

12. Won ta aso – ko ana aso sa si ibi kan

Ko eniyan gbe aso fun ni ki a ta

13. A o ni polowo – a o ni polowo oja

14. Nem keran – Yemi daran

Yemi keran – Yemi ji eran ko ninu ikoko iyare

15. Gbeborun – Tayo gbe aso iborun iyagba

Gbeborun – Tayo se ofofo

16. Ro – ki a fi nnkan si egbe kan

Ro – ki aso nnkan bi ala

Ise Asetilewa

Awon itumo wo ni a le fun oro tabi gbolohun yii:

  1. Baba gbese
  2. Wa oko gunle
  3. Ma towo bomi enu
  4. Ana ni ipari osu ojo ti ro
  5. Omo oja

Lesson note on Yoruba for SS2 Second Term – Edudelight.com

OSE KEJO

AKORI EKO: AROKO

Awon Yoruba ni awon ona ti won n gba ba ara won soro asiri ni atijo bi ati ile je pe eni ti won n so fun ko si nitori. Ami lasan ni won yoo fi ranse ti ami naa yoo si tumo ara re. Fifi ohun kan ranse bi ami lati fi aye pataki kan ye eni ti a fi ohun naa ranse sin i a n pen i aroko.

Aroko ni ami tabi ona ede ti o leje oro kan tabi ohun to duro fun nkan miiran ti a le lo lati fi ba ara eni soro lona ijinle eyi o fun wan i orisirisi itumo ti o yato si ohun ti ami naa je kii se gbogbo aroko ni a n fin ranse sin i. Awon aroko kan wa ti o je pe ibi ti yio ti rorun fun eni ti a n paroko si lati ti ri ni a n fi won si eyi yoo fun wa ni anfaani lati le tete ri.

ORISII AROKO

  1. Aroko ikilo
  2. Aroko itonisona
  3. Aroko ikede
  4. Aroko ibawi
  5. Aroko ti n fi ero inu eni han abbl

1. AROKO IKILO: Bi eniyan ba n huwa aito bii fife iyawo ile elo miiran, ole jija tabi huwa odaran tabi ika. Won le paroko ranse si iru eni bee ki o jawo tabi ki o wa toro aforiji laijebe won yoo fi ijiya ti oto si onitohun je e. Apeere:

AMI AROKOITUMO AROKO
1. Ti won ba fi iye adiye si ehinkule okunrinWon n ki lo fun pe ki ojawo ninu ajosepo pelu obinrin olobinrin
2. Eso omo osanEyi ti e ba se ni o dara
3. Ooya ti a fi n yanuIpinya de
4. EfunOye n bow a kan o
5. Ikarahun igbinOkan mi n fa si o
6. EesanIroyin buruku ni a n gbo ni pa re
7. Okuta kekereAra wa lebi okuta
8. Awo ehoroKi o yara ma salo
9. Igbo eyi nahunKi a mu oro naa ni koko
10. Ogan ese adieJe ki a ni nnkan ti a o te
11. Ajoku owuAmi iku ni, ewu n be fun e
12. Oju ejaKi a ri nkan daju
13. Eluti afin re aroA ko ri imole nkan naa daadaa
14. Awe obiOro naa pari patapata
15. EsuruOra naa ti sun mi
16. AgbayunAdun ni oran meta
17. Owo/igbaleA gba ese re kuro lako
18. Iyepe didi lewe ranseEbe tabi imule ki eniyan ma dale
19. Kanikani tuntun ati oseIyawo eni naa ti bimo tuntun
20. Fifi iye adie ranseMo n reti re kiakia
21. Eyin aja ati osunFi oro naa se soun fi raara (aja kii sa n omo re de eegun)

APEERE AROKO IKILO

AMI AROKOITUMO AROKO
1. EesanEyi tumo sip e iroyin aburu ni won gbo si eni naa
2. Ti won ba fi irepe aso obinrin ati ada ranse si okunrin miranKi okunrin naa jawo ninu ife ikoko pelu obinrin olobinrin
3. Ti ilu kan ba fi ata ati iyo ranse si ilu keji Won ti ni ikunsinu ara won tele ki won si ma mura ogun
4. Ti a ba fi esunsu ranse si eniyanAgbo pe eni naa fe dawo e le ohun kan ti ako fe ki o dawole, ki o jawo kiakia

AROKO ATONISONA: Aroko wonyi wa lati to eniyan sona ki a maa baa ko sinu ewu tabi isoro. A kii fi aroko yii ranse, ogangan ibi ti yio ti rorun fun eni ti aranse si lati ri ni an gbe won si. Apeere:

AMI AROKOITUMO AROKO
1. Ti won ba fi eeru si ori ewe ni eba onaOde kan wa nitosi ibe tabi pe o ti gba ibe koja
2. Ti won ba ta mariwo tabi aso si oju onaEnikeni ko gbodo gba oju ona naa koja nitori ewu wa nibe

OSE KESAN-AN

AKORO EKO: ORO AGBASO

Oro agbaso ni oro ti agba lenu oloro so fun elomiran ti ko si nitosi nigba ti isele tabi ipede naa waye. Eyi fara pe iroyin siso nipa ohun tabi eto kan pato. Nipa yiyi afosafo si afo agabran, awon eyo oro kookan gbodo yipada lati oro ti a gba so lenu eni ti o n safo taata. Awon wunren ti a ba nba pade ninu afo agbaran tabi oro agbaso niwonyi so wipe, ni, boya, salaye, beere, pase abbl. Bi apeere:

Bola beere boya o ti jeun

            Akin pase pe ki won bo sita kiakia

            Dosunmu so pe oun ti jeun

            Won se ajodun egbe won ni ana

            Boladale ni oun ko jo ye.

Ise Asetilewa

Yi awon afo asafo isale yii si oro agbaso

  1. Filani oju n ro mi
  2. Oluko: dide duro sibe Bosun
  3. Kolade: se o ti jeun Wole?
  4. Bimpe: Alabuburu ni mo la

OSE KEWAA

AKORI EKO: IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ASEYINWAYE

Awon Yoruba ni igbagbo ti o jinle ninu asiyinwaye (iyen leyin iku) igbagbo ninu pipada wa si aye eni to ti ku yii wan i aye atijo bee ni o si wa titi di oni.

Ni ona kinni, nibi sinku agba fi ese igbagbo yii mule. Eyi ri bee nigba ti agbalagba kan ninu idile ba ku (yala okunrin tabi obinrin) ti iyawo omo re ba wa ninu oyun ni akoko naa ti omobinrin naa ba ti mo okunrin tabi obinrin leyin iku baba tabi iya oruko ti won yoo so inu enia bee ni (ti n baje okunrin) Babatunde, Babajide, abbl. Sugbon ti o baje omobinrin, oruko ti won yio ma a pee ni Yetunde, Yeside, Iyabo ati Yejide.

Ona keji ewe awon Yoruba tun gbagbo pet i enikan ba ku nigba ti ojo re ni oye ko tii pe lati ku kii lo si orun taara se ni won yoo wa ibikan tedo si tabi ki won maa rare kiri titi ojo re yoo fipe ni aye ki o to le pada lo si orun. Iru awon ti won ba fi ojo olojo lo bayii ni a pe akudaaya tabi okutan.

Ona keta, igbagbo awon Yoruba ni pe abiku fi idi iye leyin iku mule. Abiku ni omo ti o ku, ti o tun padawa si aye, o tun le ku, ki osi tun pada waye ni igba ti o ba wuu. Atigbo nipa abiku ti wonge ikaowo reti o si je pe igbati obinrin to bii yio padabimo, ika owo mesan ni omo tuntun ti o bi gbe waye. Eyi fihan pe omo akoko ti won ge ika owo re ni o padawaye. Won a maa so oruko omo bee ni: Kokumo, Igbekoyi, Malomo, Bamitale, Durorike, Kosoko abbl.

Ona kerin, awon Yoruba tun gbagbo pea won ati egbere wa, atipe eniyan ni won to di ebora D. O Faganwa fi igbagbo yii han ninu awon iwe itan aroso. Opo eda inu itan iwe re je oro tabi owin. Inu igi bii igi iroko, igi agbalumo, inu igi ibepe, igi atisa, agbo ogede ni won ngbe. Won a si maa yipada si eniyan nigba ti o ba wunwon. Awon Yoruba tile gba pe won maa n na oja ale. Bakan naa, ni awon ogboju ode maa n royin itu ti awon ebora maa n fi won pa ninu igbo nigba ti won ba n sode ninu igbo.

Ona, karun un, awon Yoruba tun gbagbo pea won ele re omo wa. Awon omo elegbe bi eyi maa n yo obi won lenu. Aimoye won ni won n maa n loagbara won leti se obi won ni ibi. Ipese niwon maa n se fun lati tu won loju. Won ti e maa n ka eewo fun awon obi won ti won ko gbodo lana lati se bii beeko, won yoo yo iya won lenu.

Won tun gbagbo wipe awon eyan to n wo aso egungun o se eniyan lasan pe awo alagbara eyan ni won tabi ole.

Lesson note on Yoruba for SS2 Second Term – Edudelight.com

OSE KOKANLA

AKORI EKO: AWE GBOLOHUN (CLAUSE)

Awe gbolohun ni iso ti o ni oluwa ati ohun ti oluwa se. Bi apeere:

            Atoke mu omi

            Adepoju ti jeun

            Sade gun igi

Awe gbolohun le je ipede ti ko ni ju apola oruko ati apola – ise kookan lo. Apeere

            Egbeyemi ri won

            Mo gba ebun naa

            Awon ni won wa

Awe gbolohun le da duro ki o ni itumo. Bi apeere

            Ishola ati Ajani ra aso

            Omi ero naa mo

Awe gbolohun miiran le da duro ki o ma ni itumo. Bi apeere

            Ti a ba ko ile

            Iba ke si mi

Awon eyi ni a mo si awe gbolohun afarahe ti won ko le da duro laisi olori awe gbolohun.

Awe gbolhun le da duro bi odidi gbolohun, iru awe gbolohun bee ni a n pen i olori awe gbolohun. Bi apeere:

            Ade mo

            Abeke gbon

            Bisi rerin-in (Bisi ni oluwa, rerin-in ni koko gbolohun to so nkan ni oluwa)

Awe gbolohun kii ju apola oruko ati apola ise kan lo. Bi apeere:

Apola oruko (Noun Phrase)                            Apola – ise (Verb Phrase)

Bola                                                                 wa lanaa

Joonu igbe hin adun                                        gbe apore si le

ORISII AWE GBOLOHUN (TYPES OF CLAUSE)

1. Olori Awe Gbolohun (Main Clause): eyi le da duro ti le kuro nibe. Ofi ihun jo gbolohun abode tobi gbolohun eleyo oro – ise. Apeere.

Awon omode feran iresi

            Aja ogundeji ku

            Ise dara

            Gbadamosi gun iya re

2. Awe Gbolohun Afaiahe: Inu ihun gbolohun opolo oro – ise tabi oniba ni a ti maa n ri awe gbolohun afarahe. Eyi ni awe gbolohun ti ko le da duro ki o si fun wa ni itumo ayafi ti o ba fi ara ti olori awe gbolohun. Ona meta ni awe gbolohun pin si, awon ni:

i. Awe gbolohun afarahe asapejuwe: Eyi maa n tele oro – oruko tabi apola oruko ‘t’ ni atoka tabi ami je ki a mo nipa apejuwe nkan. Bi apeere:

            Apinke ti o sun ti dide

            Aso Ankara ti mo ra dara

            Omoge ti mon soro re niyi

ii. Awe gbolohun afarahe asodoruko: ‘pe’ ni o maa n be re aye gbolohun yii, o le sise oluwa ati abo. O si maa n sise isodoruko ninu ihun gbolohun won maa n pen. Apeere:

            Aja naa ku ni gba ti oko ko luu

            Emi yoo lo nisinsinyii ti mo gbo pe won de

            Bolaji fa oju ro nitori inu re ko dun

            Ole naa ku nigba ti olopaa kolu won

Ise Asetilewa

OSE KEJILA

AKORI EKO: ARANMO ATI ISINKU

Aranmo ni agbara ti iro kan ni lori iro miiran eyi ti o le f ape ki iro mejeeji yi pada di iru kan naa tabi ki won fi abuda jo ara won lona miiran a le pe aranmo ni agbara ti iro kan ni lori miiran lati so di ni ara re. ki aranmo to le waye, oro meji gbodo fe gbe kegbe. Faweli yoo pari oro akoko faweli yoo si beere oro keji. Bi apeere.

            Ku + ile = kuule

            F1    F2

Iye ohun tabi silebu oro mejeeji ni o gbodo wa ninu ayo risi (oro aranmo). Apeere yii fihan pe faweli ‘I’ to bere oro keji ni gbogbo abuda faweli ‘u’ eyi si so faweli ‘I’ ati ‘y’.

IPO AFARANMO ATI IRO AGBARANMO

Iro afaranmo: eyi ni oro ti o ni agbara lati yi abudaa iro tabi die lara abuda iro miiran pada si tire.

Iro agbaranmo: iron i o yi pada ti o gba abudu iro miiran. Apeere:

            Ile + iwe           = ileewe

            Ara + ile           = araale

Iro faweli apeere oke ti o bere oro keji ninu apeere oke yii ni iro agbaranmo.

ORISII ARANMO

  1. Aranmo iwaju
  2. Aranmo eyin
  3. Aranmo alaiforu
  4. Aranmo aforo
  5. Aranmo kikun

1. ARANMO IWAJU: Eyi ni igba ti iro faweli ti o pari oro akoko ti o je iru afaranmo ba ran mo nro faweli ti o bere oro keyi ti ale to ka si gege bi iro agbaranmo. Bi apeere:

Iro afaranmo               Iro agberanmo                        Aranmo iwaju

Ara                               + ile                                         araale

Apo                              + iyo                                        apooyo

Owo                             + ise                                         owoose

Etu                               + ibon                                      etunbon

Ile                                + iwe                                        ileewe

2. ARANMO EYIN: Ni igba ti I n faweli ti o bere oro keyi ba ranmo iro faweli ti o pari oro akole. Apeere:

Iro afaranmo               Iro agbaranmo                        Aranmo eyin

Ara                               + oko                                       araooko

Ku                                + ale                                        kaale

Omo                            + oko                                       omooko

3. ARANMO ALAIFORO: Eyi ni igba ti iro afaranmo ati iro agbaranmo ba tele ara won taa ra laije pe iro miiran jeyo laarin won. Bi apeere:

            Iya ile ====== iyaale

            Agba etu ====== agbeetu

            Ara eko ====== areeko

4. ARANMO AFORO: Ni igba ti iru miiran ba jeyo laarin iro faweli afaranmo ati iro faweli agbaranmo. Eyi wopo ninu ihun afomo ibere “ori” ati oro-oruko ninu eyi ti faweli ‘o’ ninu ‘oni’ ti maa n gbaranmo lara faweli ti o bere oro oruko konsonanti ‘n’ gbodo di ‘l’.

OSE KETALA

AKORI EKO: APOLA NINU EDE YORUBA

Apola je okan ninu awon abala ihun gbolohun ede Yoruba. Gbolohun re je eyo oro kan tabi akojopo. Ihun ede Yoruba da bi igba ti a bat i hun eni, a ni idi ti awon oro wonyi jo lona ti yoo fi le e mu itumo ti o gbamuse lowo, atun le fi we, tilo awon ohun elo ikole jo lorisirisi lona ti yoo le fi gbele ti o dara ti o si lewa jade.

Lara awon isori oro ti a to jo lati hun gbolohun ede Yoruba ni.

  1. Oro – oruko
  2. Oro aropo – oruko
  3. Oro – ise
  4. Oro apejuwe
  5. Oro aponle
  6. Oro asopo abbl.

AWON APOLA INU EDE YORUBA

1. Apola Oro – oruko (Noun Phrase): Eyi le je oro kan tabi akojopo oro ti a maa n lo gege bi oluwa ati abo ninu gbolohun yala pelu eyan tabi laisi eyan. Ihunapola oruko leje:

a. Oro – oruko kan soro pere. Apeere:  Ojo ro

b. Oro – aropo oruko. Apeere: Mo sun

d. Oro – aropo afarajoruko. Apeere: Eyin ni mo ri

e. Apola oro – oruko pelu eyan. Apeere:

            Okunrin yen ni o mu

            Ewure merin ni won pa bo ifa

            Bola aburo Kemi ti wolu de

            Ounje die niki ose

e. Apapo oro – oruko ati awe gbolohun. Apeere:

            Oro ti Kemi so dun won

            Aso ti a ra ti gbo

2. Apola Oro – ise (Verb phrase): Apola oro ise le je eyo oro tabi akojo po awon eye. Oro ti o  n so ohun ti oluwa se ninu awe gbolohun ati ninu odidi gbolohun o le je oro –ise ponbele, oro – ise agbabo ati asaaju oro – ise. Oun ni on sise opomulero ninu ihun gbolohun ede Yoruba. Apeere: jokoo, sare, jade, dide abb.

Ta iyan, je efo sese de ijankon, gbinododo

3. Apola Aponle (Adverb phrase): Eyi ni oro ti o n se ise epon/eyan fun oro – ise ninu gbolohun ede Yoruba apola aponle maa n fi itumo ti o kun fun oro – ise, inu apola ise ni apola aponle ti maa n jeyo. Fun apeere:

            Ori tan yeri yeri

            O n rin kemokemo

            Aso funfun balau

Ise Asetilewa

Ko apola ede Yoruba ti okookan gbolohun isale ti a fa ila si nidi je.

  1. Bisi Adepegba lo si oja
  2. Omo ti a n soro re ti de
  3. Eran dindin ni mo je lanaa
  4. Adebayo mu oti yo
  5. Badejo pa eran oya
  6. Iginaa ga fiofio
  7. Soja yan jaujau
  8. Emi ati eyin ni won pe
  9. Dokita oyinbo gun abere mefa

AKORI EKO: AWON OHUN ELO IFA DIDA

1. IKIN: Orisiirisi ni awon ohun elo ifa dida ti o wa. Awon ti o se pataki julo ninu won ni ikin, opele, ibo, iroke, opon ifa, agere ifa, apo ifa, ilu ifa (orisiirisi) opa orere. Ikin lo se pataki julo ninu awon nnkan wonyi nitori pe oun gan-an ni Orunmila fi ropo araa re leyin igba ti o ti pada lo si ode orun ti ko si wa sile aye mo. Ninu agere ifa tabi awo ifa ni a maa n ko ikin si nibe ni a si ti maa n bo o gege bi oosa.

2. OPELE: Nnkan meji pataki ti a fi n da ifa ni opele, omo ni opele je fun ikin sugbon o wulo pupo nitori pe o rorun lati da ifa. Omo mejo ni opele bi, merin ni apa otun, merin ni apa osi. Okookan ninu awon omo wonyii ni o ni inu ati eyin.

3. IBA: Bi a ba ti da ifa kale tan ti a si ti mo odu ti o jade, a maa lo iba lati wa idi odu yii dele kodoro. A le fii mo eni gan-an ti odu yii jade si, bi eni ti o waa dafa gan-an ni o tabi eeyan re kan. A tun maa n lo ibo lati yan ebo ati lati beere lowo ifa ibi ti a o gbe ebo naa si. Orisiirisi ibo lo wa. Pataki julo nibe ni egungun ati owo eyo. Egungun duro fun bee ko owo eyo duro fun bee ni.

4. IROKE: Iroke je ohun elo ifa dida ti a fi n pe Orunmila bi a bat i n da ifa lo. A tun maa n pee ni irofa. Eyin erin ni a fi n gbe iroke sugbon a le fi ide tabi igi lasan gbee.

5. OPON IFA: Orisii opon ifa lo wa, omiran ri roboto, omiiran ni igun merin. Bi babalawo ba fi ikin da ifa, dandan ni ki won o ni opon ifa ninu eyi ti won o maa tee si. Iyerosun ni a maa n ko sinu opon yii, ninu re si ni a ma ate ifa si.

6. AGERE IFA TABI AWO IFA: Ninu awo yii ni awon babalawo maa n ko ifa si. Won maa n fi igi gbe agere ifa pelu ideri re, nitori pe ibe ni a n ko ikin ti o duro fun Orunmila si, awon gbenagbena ni lati fara bale gbee ki won o si se ona ti o jojunigbese sii lara.

7. APO IFA: Ona pataki kan ti a fi le da babalawo mo ni nipa apo ti won maa n fi ko si ejika. Ninu apo yii ni won maa n ko gbogbo ohun elo ifa dida si. Babalawo kii rin ko san wo ifa. Aso ni a fi se apo yii sugbon maa fi kikada ileke, olowo iyebiye hun apo ifa miiran.

8. ILU IFA: Oroorun tabi nigbakugba ti won ba fe se ariya, bibo ifa tabi se etutu. Ilu ifa ti won maa n lo ni aran tabi ipese.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button