Lesson Note Yoruba SS1 Third Term
Yoruba lesson note for Secondary School – Edudelight.com
YORUBA SCHEME OF WORK FOR SS ONE THIRD TERM
ILANA ISE FUN SAA KETA FUN OLODUN KIN-IN-NI (SSONE)
OSE KIN-IN -NI: EDE: ISORI ORO- ORO ORUKO
- ORIKI
- ORISI ORO ORUKO
- ISE TI ORO ORUKO N SE NINU NINU GBOLOHU
ASA: ASA ISOMOLORUKO NI ILE YORUBA
- ORUKO AMUTORUNWA
- ORUKO ABISO MO ESIN TABI ISE,IDILE,ABIKU abbl
- ORIKI
- INAGIJE
LITIRESO: ITUPALE EWI APILEKO
OSE KEJI: ISORI ORO- ORO AROPO ORUKO
- ORIKI
- ILO ORO AROPO ORUKO NINU GBOLOHUN
ASA: IPOLOWO OJA
- IWULO ATI PATAKI IPOLOWO OJA
- ORISIRISI ONA IPOLOWO OJA
LITIRESO: ITUPALE ASAYAN IWE TI IJOBA YAN
OSE KETA: EDE: ISORI ORO:
- ORIKI ORO ISE
- ORISI ORO ISE
- LILO ATI DIDA WON MO NINU GBOLOHUN YORUBA
ASA: ERE IDARAYA:
- ERE OSUPA
- ERE OJOJUMO
- ERE ITA GBANGBA
- ERE ABELE
LITIRESO: ITUPALE ASAYAN IWE TI IJOBA YAN
OSE KERIN: EDE: ONKA YORUBA LATI EGBAA DE EGBAARUN – UN
(2000-10,000)
ASA: ERE IDARAYA
LITIRESO: ITUPALE ASAYAN IWE TI IJOBA YAN
OSE KARUN-UN: EDE: AROKO AJEMO-ISIPAYA
ASA: ERE IDARAYA; ERE IGBALODE
LITIRESO: ITUPALE ASAYAN IWE TI IJOBAYAN
OSE KEFA: EDE: ISORI ORO
- ORO AROPO AFARAJORUKO
- LILO WON NINU GBOLOHUN
ASA: OWO YIYA
LITIRESO: EWI ALOHUN GEGE BI ORISUNIRONU YORUBA
OSE KEJE: EDE: ITUPALE GBOLOHUN ONIPON-ON-NA
- ITUPALE PON-ON-NA
- DIDA GBOLOHUN MO
- TITOKA ITUMO ORISIRISI TI PON-ON-NA NI
ASA: ONA TI A N GBA GBESE
LITIRESO: EWI ALOHUN GEGE BI ORISUN AGBARA ATI IMO IJINLE
Y ORUBA
OSE KEJO: EDE: AROKO ASARIYANJIYAN
ASA: ASA ISINKU NI ILE YORUBA
LITIRESO: EWI ALOHUN TO JE MO ASA ISINKU
OSE KESAN-AN: EDE: AKAYE OLORO GEERE
ASA: ASA ISINKU NI ILE YORUBA
LITIRESO: AKOJOPO AWON OWE TI JEYO LATI INU IWE
ASAYAN EWI TI AJO WAEC/NECO YAN
OSE KEWAA: EDE: AROKO – LETA KIKO (LETA GBEFE)
ASA: ASA ISINKU
LITIRESO: ITUPALE ASAYAN IWE TI IJOBA YAN
OSE KONKANLA: ATUNYEWO EKO LORI ISE NINU EDE, ASA ATI
LITIRESO
OSE KEJILA: AKANSE IDANWO LORI ISE SAA YII NINU EDE, ASA ATI
LITIRESO
OSE KIN-IN-NI
EKA ISE: EDE
ORI ORO: ISORI –ORO (ORO- ORUKO)
Ise ti oro Kan ba n se ninu gbolohun ni a le fi pin in si isori oro ti o ye ninu gbolohun. Isori oro Yoruba ni wonyii;
- Oro oruko(noun)
- Oro ise(verb)
- Oro aropo oruko(pronoun)
- Oro aropo oruko afarajoruko(prominal )
- Oro atokun(prepositional noun)
- Oro eyan/apejuwe (adjective)
- Oro asopo(conjuction)
ORO ORUKO
Oro oruko ni oro ti o le da duro ni ipo oluwa, abo ati eyan ninu gbolohun
Orisi oro oruko
- Oro oruko eniyan- apeere; Ayinde, Akanni, Adufe, Kolawole, Durojaye Yejide ,Tobiloba abbl
- Oruko alaiseeyan– apeere; omi, igi, iwe, aga
- Oruko ohun eleemii– apeere;eniyan,eranko,
- Oruko ohun alaileemii– apeere;aga, omi, igi, ile
- Oruko ohun aseeka– apeere; iwe,ile, oko, bata
- Oruko ohun alaiseeka– apeere;epo, iyanrin, omi, iyo, gaari, irun ori,afefe
- Oruko ohunafoyemo- apeere;Alaafia,imo, ife, ogbon,ibanuje,ayo
- Oruko ohun aiseda- apeere; omi, ile,omo,
Ise ti oro oruko n se ninu gbolohun
Ipo ti oro oruko ba ti jeyo ninu gbolohun ni a fi n toka ise won
- Oro oruko n sise oluwa: eyi ni oluse nnkan ninu gbolohun. Ibeere gbolohun ni o ti maa n jeyo. Apeere;
- Kunle pa ejo
- Oluko koi se si oju patako
- Oro oruko n sise abo: eyi ni olufaragba ohun ti oluwa se ninu gbolohun. Aarin tabi ipari gbolohun ni eyi ti maa n jeyo.apeere;
- Baba ra oko
- Tuned lo si Ibadan ni ana
Oro oruko n sise eyan : nigba ti oro oruko meji ba tele ara won ninu apola oruko,oro oruko keji ni yoo je eyan fun oro oruko akoko.o le je ni ipo oluwa tabi abo. Apeere;
- Okunrin olowo se ayeye ojo ibi re lana
- Mo ri aja ode
- Eran bokoto ni mo je ni ana
Igbelewon:
- Ko isori oro Yoruba
- Kin ni oro oruko?
- Pelu apeere ko orisi oro oruko marun-un
- Salaye ise ti oro oruko n se ninu gbolohun pelu apeere
Ise asetilewa:
- Pelu apeere mete mete, salaye ise oro oruko meta ninu gbolohun.
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ASA ISOMOLORUKO NI ILE YORUBA
Asa isomoloruko je ona ti a n gba fun omo tuntun ni oruko ti yoo maa je titi lae ni ile Yoruba
Gbogbo ohun ti Olodumaare da saye ni o ni oruko, ibaa se ohun abemi tabi ohun ti ko ni eemi. Idi niyi ti awon agba fi n so pe, “ile la n wo ki a to so omo ni oruko”
Orisirisi oruko ti awon eniyan n so omo tuntun
- Oruko amutorunwa
- Oruko abiso
- Oruko idile
- Oruko abiku
- Oruko inagije
- Oriki
- Oruko Amutorunwa: Eyi ni oruko ti a n so awon omo ti o gba ona ara waye tabi ti won mu nnkan ara waye lara won ni ile Yoruba. Apeere oruko bee ni; Ibeji,Oke,Dada,Olugbodi,Ige
- Oruko Abiso: Yoruba a maa wo ile,igba,asiko,ipo ti obi wa,ibi ti a bi omo si lati fun omo tuntun ni oruko.apeere;
- Oruko ajinde– Babajide,Babatunde,Iyejide,Iyetunde,Iyabode
- Oruko asiko odun: Abiodun,Bodunde, Bodunrin
- Oruko omo ti a bi si oke okun: Tokunbo
- Oruko omo ti a bi si ona: Abiona
- Oruko Abiku: Oruko yii pin si ona meji;
- Oruko ebe:Dorojaye, Omolanbe, Matanmi, Akisatan, Duroriike
- Oruko abuku: Aja , Kilanko, Omitanloju
- Oruko idile: Omoboola, Oladoye, Oyekunle, oyekanmi, Adebiyi
- Oruko inagije: Eyi ni oruko ti eniyan n fun ara re lati buyi kun iwa omoluabi re tabi eyi ti won fun eniyan kan nitori iwa ipanle. Apeere;
Olowomojuore, Olowojebutu, Owonifaari, Ekun, dudumaadan
- Oriki: oriki je oruko miiran ti Yoriba n so omo lati fi mo orile tabi idile ti o ti jade ati lati se koriya fun omo.Apeere; Alamu, Asake, Akanni, Asunle, Adufe, Awele, Apeke
Igbelewon:
- Fun asa isomoloruko loriki
- salaye orisi oruko ti yoruba n so omo tuntun pelu apeere meji meji.
Ise asetilewa:
- ko oruko inagije marun-un pelu itumo.
EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: ITUPALE EWI APILEKO TI IJOBA YAN
OSE KEJI
EKA ISE: EDE
ORI ORO: ISORI ORO ORUKO- ORO AROPO ORUKO
Oro aropo oruko ni awon oro ti a n lo dipo oro oruko ninu gbolohun
Abuda oro aropo oruko
- Oro aropo oruko maa n ni eto eni: eyi ni eni kin in ni,eni keji ati eni keta ni ipo oluwa,abo ati eyan ninu gbolohun
- Eni kin- in- ni ni eni ti o soro ninu gbolohun.apeere;
Mo n jeun
- Eni keji ni eni ti a n ba soro ninu gbolohun.apeere,
O n korin
d. Eni keta ni eniti a n soro nipa re ninu gbplohun.Apeere,
O n kawe
BI A SE LE LO ORO AROPO ORUKO NINU GBOLOHUN
- Ipo oluwa: Eni Eyo Opo
Kin-in-ni mo a
Keji o e
Keta o won
- Ipo abo: Eni Eyo Opo
Kin-in-ni mi wa
Keji o/e eyin
Keta Afagun faweeli won
ti o keyin oro ise
- Ipo eyan: : Eni Eyo Opo
Kin-in-ni mi wa
Keji re yin
Keta re won
Igbelewon:
- Fun oro oropo oruko loriki
- Salaye abuda oro aropo oruko pelu apeere
- Pelu ate oro aropo oruko, salaye bi a se le lo oro aropo oruko ninu gbolohun.
Ise asetilewa:
Mu apeere oro aropo oruko meji ni ipo oluwa,abo ati eyan ki o si lo o ninu gbolohun.
EKA ISE: ASA
ORI ORO: IPOLOWO OJA
Ipolowo oja ni orisirisi ona ti a n gba se aponle oja nipa kike gbajare re si etigbo awon eniyan ati lat fa won mora.
Ipolowo oja ni agunmu owo.
Iwulo ati Pataki ipolowo oja
- Ipolowo oja ma n je ki oja ti oloja n ta di mimo fun ogooro eniyan yala ni tosi tabi ni ona jinjin
- O maa n je ki awon onraja ri nnkan ra ni arowoto won
- O maa n je ki awon onraja ni anfaani lati ye oja ti won f era wo
- O maa n je ki oja ti ontaja n ta ki o ya ni kiakia
Orisirisi ona ipolowo oja ti abinibi
- Ipate: ni aye atijo awon oloja a maa pate oja si oja,ikorita,iwaju ile,ni ori eni,ori kanta tabi konker,ona oko.apeere irufe oja ti won maa n pate ni; ire oko bii; isu,agbado,ogede,oronbo. Bakan naa, won a maa so eran osin mole ni ori iso lati ta
- Ikiri: Awon oloja a maar u oja le ori kiri lati ta,bee ni won a maa se aponle oja naa nipa kike gbajare si etigbo awon eniyan.apeere oja bee ni; epa atio guguru, nnkan iserun lorisirisi, eko gbigbona aso abbl
- Ohun enu: Eyi ni lilo ohun enu lati so oja di mimo fun onraja
Igbelewon:
- Kin ni ipolowo oja?
- Ko Pataki/iwulo ipolowo oja marun-un
- Salaye ona ipolowo oja abinibi.
Ise asetilewa:
- Salaye ona ipolowo oja ode oni meji lekun- un rere
OSE KETA
EKA ISE: EDE
ORI ORO : ISORI ORO- ORO ISE
Oro ise ni koko fonran ti o n toka isele tabi nnkan ti oluwa se ninu gbolohun.
Oro ise ni opomulero gbolohun, lai si oro ise ninu gbolohun, ko le ni itumo.
Oro ise ni o maa n fun wa ni imo kikun nipa ohun ti oluwa se ninu gbolohun.
Orisi oro ise
- Oro ise kikun
- Oro ise agbabo
- Oro ise alaigbabo
- Oro ise asodidi gbolohun
- Oro ise eleyo oro ise(ponbele)
- Oro ise alakanpo
- Oro ise elela
- Oro ise alailela
Bi a se le lo awon oro ise wonyi ninu gbolohun ati bi a se le da won mo
- Oro ise kikun: Eyi ni eyo oro ise eyokan ti o ni itumo ninu gbolohun.apeere;
- Yemi sun
- Adufe jeun
- Folake korin
- Oro ise agbabo: Eyi ni oro ise ti won ko le sai gba abo(oro orruko) ninu gbolohun.apeere;
- Mo ra oko
- Anike ta ile
- Kilanko fe iyawo
- Oro ise alaigbabo: A kii lo oro abo pelu oro ise yii.apeere;
- Olodumare dara
- Igbeyawo dun
- Alamu jo
- Oro ise asodidi gbolohun(oro apase):Awon oro yii maa n waye bii gbolohun ase bakan naa won le duro bii gbolohun.apeere;
Wa, jokoo, dide, jade
- Oro ise alakanpo: A le pe oro ise yiii ni ‘Asinpo’. Eyi ni ki oro ise to bii meji tabi ju bee lo ninu gbolohun.apeere;
- Ole ko obe je
- Ologbo pa eku je
- Ige je ewa yo
- oro ise elela:Eyi ni awon oro onisilebu meji sugbon ti a le la sim meji lati fi oro miiran bo o ni aarin ti a sit un le lo won ti a ko ba fi oro miiran bo o ni aarin.apeere;
- Mo gba Oluwa gbo (Gbagbo) – mo gbagbo
- Jesu gba baba naa la (gbala) – Jesu gbala
- Esu tan Eefa je (tanje) – Esu tanje
- Oro ise alailela: a ko le la awon oro ise wonyii si meji,odidi ni won maa n wa ninu gbolohun.apeere;
- Fola subu lule
- Oyindamola siwo ise
- Bisola feran owo
Igbelewon:
- Fun oro ise loriki
- Ko orisi oro ti o wa ninu ede Yoruba
- Salaye pelu apeere bi a se le lo awon oro ise wonyi ninu gbolohun.
Ise asetilewa:
- Ko apeere oro ise alailela marun-un.
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ASA – ERE IDARAYA
Ere idaraya ni awon ere ti tewe tagba n se lati mu ki ara won ji pepe ni ile Yoruba. Bi akoko ise se wa bee ni won ni akoko fun ere idaraya. Akoko ti owo ba dile ni won maa n se ere idaraya. Tomode – tagba ni ere idaraya wa fun ni ile Yoruba
Isori Ere Idaraya Laaarin Awon Yoruba
- Ere ojoojumo
- Ere osupa(ere ale)
Ere ojojumo: eyi ni ere ti tomode tagba maa n se ni owo osan si irole. O pin si ona meji;
- Ere Abele: apeere ere yii ni: ere ayo tita,mo-ni-ni –mo-ni – ni , booko-booko
- Ere itagbangba: apeere ere yii ni; ere ijakadi, ere aarin, ere ayo tita
Ere osupa: eyi ni ere ti awon omode maa n se ti ile ba tis u ni akoko ere osupa nitori aisi ina monamona ni aye atijo. Apeere irufe awon ere yii ni; ere bojuboju, ekun meran, isa- n-saalubo, eye meta tolongo waye, kin ni n leje?, alo lorisirisi abbl
Ni kukuru,ere sise wopo laaarin Yoruba paapaa julo nigba ti owo ba dile. Ere ayo tita je ere awon agba to kun fun ogbon ati opolopo iriri,omode ti o ba si mo ayo ta awon agba Gbagbo pe ologbon omo ni.
Apeere orin ere idaraya;
Ekun meran
Lile: ekun meran Egbe: meee
O tori bogbo meee
O torun bogba meee
Oju ekun pon meee
Iru ekun n le meee
O fe mu o meee
Ko ma le mu o meee
Ekun meran meee
Ekun meran meee
Ekun meran meee
Kin ni n leje
Lile: kin ni n leje Egbe: lenjelenje
Ewure n leje lenjelenje
Aguntan n leje lenjelenje
Obuko n leje lenjelenje
Adiye n leje lenjelenje
Okuta n leje iro n la
Akiti lo le ja:
Ele: Akiti lo le ja o
Egbe: ija lo le ja o
Ele: o gbe para o fi da
Egbe: ija lo le ja o
Ele: O ro ki bii ibon
Egbe: ija lo le ja o
Igbelewon:
- Fun ere idaraya loriki
- Salaye isori ere idaraya laaarin awon Yoruba pelu apeere orin ere naa.
Ise asetilewa:
- N je ere idaraya ode oni dara ju ere idaraya abinibi? Tu keke oro.
Yoruba lesson note for Secondary School – Edudelight.com
OSE KERIN
EKA ISE: EDE
ORI ORO: ONKA YORUBA LATI EGBAA DE EGBAARUN –UN
(2000-10,000)
Onka ni ona ti Yoruba n gba lati ka nnkan ni ona ti o rorun.
Eyi ni bi a se n se isiro nnkan ni ilana Yoruba.
Yoruba ni oniruuru ona ti won n gba lati kai ye nnkan ni aye atijo nitori won Gbagbo pe ko si nnkan ti a ki n ka bi o tile je pe “a kii ka omo fun olomo bee ni a kii toju onika- mesan-an kaa”. Yoruba a ma aka ile , oko, ebe, ika owo ati awon eya Ara gbogbo. Won a maa se amulo ilana aropo (+), ayokuro (-) ati isodipupo (*) ninu isiro won
Ilana onka lati egbaa titi de egbbrun-run
2000(200*10) – igba mewaa – egbewa/egbaa
2200(200*11) – igba mokanla- egbokanla
2400(200*12) – igbamejila – egbejila
2600(200*13) – igba metala – egbetala
2800(200*14) – igba merinla – egberinla
3000(200*15) – igba meedogun – egbeedogun
3200(200*16) -igba merindinlogun – egberindinlogun
3400(200*17) -igba metadinlogun – egbatadinlogun
3600(200*18) -igbamejidinlogun – egbejidinlogun
3800(200*19) -igba mokandinlogun – egbokandinlogun
4000(200*20) -ogun igba – egbaaji
4200(200*21) -igbamokanlelogun – egbokanlelogun
4400(200*22) -igba mejilelogun – egbejilelogun
4600(200*23) -igba metalelogun – egbetalelogun
4800 (200*24) – igba merinlelogun – egberinlelogun
5000 (200*25) -igba meedogbon – egbeedogbon
6000 (2000*3) -egbaa Meta – egbaata
8000 (2000*4) -egbaa merin – egbaarin
10000(2000*5) – egbaa marun-un – egbaarun-un
Igbelewon:
- Fun onka loriki
- Ko onka Yoruba lati egbaa de egbaarun-un
Ise asetilewa:
- Salaye ni kukuru bi awon baba nla wa se n ka nnkan laye atijo pelu irorun ki imo mooko-mooka to de ile wa.
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ERE IDARAYA
OFIN ERE IDARAYA KOOKAN
ERE AYO TITA:
- Eniyan meji pere lo n tayo
- Apa otun ni a n ta ayo si ninu iho kookan
- A ko le je ninu iho ti omo ayo ba ti ni ju meta lo
- Iran ni awon osefe maa n wo,won ko gbodo da si ayo
- A kii ta ayo ni owuro
Ere ekun meran
- Eni kan ni o gbodo se ekun tabi eran
- Osere ko gbodo po ju loju agbo ere
- Ekun ko gbodo mu eran ninu agbo ayafi leyin agbo
- Awon osere ni apapo ko gbodo ja rara
Kin ni n leje
- A ko gbodo so pe nnkan ti ko ni eje ni eje
- Itiju nla gbaa ni fun eni ti o ba so pe nnkan ti ko ni eje leje gege bii ijiya ese re,awon elegbe re yoo ho hee lee lori
Ohun elo, anfaani ati ewu ti o wa ninu ere kookan
Ayo tita: opon Ayo, omo Ayo
Anfaani
- Ayo tita n mu ni ronu jinle
- O n je ki a mo nipa oro ati itan atijo
- Erin ati awada maa n waye ni idi ere ayo
- Diduro ni idi ere ayo maa n yo ni kuro ninu ewu ti eniyan le ba pade latari rinrin kiri
Ewu
- Orisi iwosi maa n waye ni idi ayo
- O maa n gba ni lakoko
Ere ekun meran: agbo ere, eniyan meji ti yoo se ekun ati eran, awon omo agbo
Anfaani
- n fun eniyan ni okun ati agbara
- n fi isora ati iyara ko ni
- O n ko omode ni ogbon inu lati le bo lowo ewu ati ota
- O n ko omode lati le da aabo bo egbe won to wa ninu ewu ati lowo ota
- O maa n mu ki emi ife ati isokan gbooro si lokan awon omode
Ewu: awon osere le subu ki won si farapa loju ere
Igbelewon:
- Fun ere idaraya loriki
- Ko ofin ti o de ere ibile kookan
Ise asetilewa:
- Awon ofin wo lo de ere boolu afesegba ti ode oni? Ko ofin marun-un
OSE KARUN-UN
EKA ISE: EDE
ORI ORO: AROKO – AROKO AJEMO-ISIPAYA
Aroko ni ohun ti a ro ninu okan wa ti a si se akosile re
Aroko kiko ninu ede Yoruba gba ironu jinle,a ko le ko aroko sile lai je pe a fi oye ati ogbon inu ko o
Orisi aroko kiko
- Aroko onileta
- Aroko alalaye
- Aroko onisorogbesi
- Aroko asapejuwe
- Aroko alariyanjiyan
- Aroko oniroyin
- Aroko ajemo isipaya
AROKO AJEMO ISIPAYA
Aroko ajemo isipaya je aroko ti o gba sise alaye lekun-un-rere nipa nnkan ayika eni
Aroko yii je alaye kikun nipa ori oro kan,idi niyi ti o fi je pe akekoo ni lati ma aka iwe jona(journals), iwe iroyin(news papers) ,iwe ede iperi(dictionaries) ati awon iwe miiran ti yoo fun won ni imo kikun nipa ohun ti o n sele ni ayika won
Ori oro to jemo aroko ajemo isipaya
- Ounje ile wa
- Ise tisa
- Imototo
- Iwa lewa
- Eko ile
- Atelewo eni kii tan ni je
- Iwa rere leso eniyan abbl
Igbelewon:
- Kin ni aroko?
- Ko orisi aroko ede Yoruba
- Fun aroko ajemo-isipaya loriki
- Ko ori oro marun-un ti o je mo aroko ajemo-isipaya
Ise asetilewa:
- Ko aroko ajemo isipaya lori ori “Imototo”
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ERE IDARAYA IGBALODE
Ere idaraya je ere ti tewe tagba maa n se lati mu ki ara won ji pepe.
Gbogbo ere idaraya abinibi ile Yoruba lo je ere ti a fi n naju, ti o n da ni laraya ti o si n ko ni lekoo.
Awon ti ara won ya, ti ara won pe lo maa n se ere idaraya ni ile Yoruba nitori awon ere wonyii ko si fun abirun tabi alaipe ara rara.
Ni ode – oni, opolopo awon ere idaraya abinibi ni a ti pati si egbe kan ti a ko se mo.awon ere idaraya ti awon oyinbo alawo funfun ko wa si ile wa ni a ti fi dipo awon ere abinibi wonyi ti ko si ye ki o ri bee
Awon ere igbalode ni wonyi:
- Draft – ere ayo
- Football – ere afesegba
- Wrestling – ere ijakadi
- Boxing – ese kikan
- Taekwondo – eke mimu
- Athletic :
- Running – ere sisa
- Walking – irin rinrin
- Jumping – fifo soke
- Throwing – shotput,discuss, hammer throw, javelin throw- nnkan jiju
- Tack and field – ere sisa lori ila
AYIPADA TO DE BA ERE ABINIBI
Nitori awon Yoruba nife si ohun ti o wa lati odo awon alawo funfun ju ohun ti o je ti ile wa lo,opo ti pa awon ere abinibi ile wa ti si apa kan ti won si room ti igbalode. Iwadii fi han pe ko si iyato kan gboogi laaarin ere abinibi ati ti igbalode ti awo oyinbo mu wa si ile wa. Ki adiye to ma je agbado, nnkan Kan ni o ti n je tele ni awon ere igbalode je ni ile wa.
Awon ohun elo ti awon oyinbo n lo ninu ere yii ni o yato si ti abinibi ati ona ti a n gba se e.
Ni kukuru, ere idaraya abinibi ati ere idaraya igblode ni o n koni; logbon, ete, o n muni ronu jinle, o n je ki ara wa da sakasaka, o n mu wa mo nipa oro ati itan atijo, o n je ki a ni ife si omonikeji wa, o n pani lerin, o n je ki a di alagbara ki a si ni aya lati koju isoro.
Igbelewon:
- Fun ere idaraya loriki
- Ko awon ere idaraya ode-oni pelu oruko ti a mo won mo ninu ere idaraya abinibi
- Salaye ayipada ti o de ba ere idaraya abinibi
Ise asetilewa:
- Ni tire, salaye awon ayipada ti o ro wi pe o de ba ere idaraya abinibi
Yoruba lesson note for Secondary School – Edudelight.com
OSE KEFA
EKA ISE: EDE
ORI ORO: ISORI ORO – ORO AROPO- AFARAJORUKO
Oro aropo afarajoruko je oro ti a n lo dipo oro oruko sugbon ti o fi ara jo oro oruko.
Isesi oro aropo afarajoruko ko yato si ti oro oruko.
Ninu Ede Yoruba mefa pere ni awon oro aropo afarajoruko. Awon niyi
Eni Eyo Opo
Kin- in – ni emi awa
Keji iwo eyin
Keta oun awon
Abuda oro aropo afarajoruko
- Oro aropo afarajoruko se e pin si eto eni kin in ni, enikeji ati eni keta. Apeere;
- Emi ni mo gbee
- Iwo lo fa a
- Oun ni o soro
- O se e pin si eto iye, eyi eyo tabi opo. Apeere;
- Emi naa
- Awon agbaagba
- Oun yii
- Awa niyi
- O le gba eyan ninu apola oruko.Apeere;
- Oun naa ti dagba
- Awon wonyi ko gbawe
- Eyin yii ko fe ise se
- A le lo oro asopo “ati” lati so oro aropo afarajoruko meji po. Apeere;
- Emi ati oun pa eye owiwi
- Awa ati eyin feran Olodumare
- O le jeyo pelu awon wunren bii; ko , da, ni, nko. Apeere;
- Iwo da?
- Awon ko
- Emi n ko?
- Awon ni
- Oro aropo afarajoruko “oun” se e lo bi oro asopo fun oro oruko meji ninu gbolohun. Apeere;
- Bola oun Bisi je eba
- Anike oun Tade pa eran igala
- A le gbe oro aropo afarajoruko saaju wunren alatenumo “ni” lati pe akiyesi . Apeere;
- Eyin ni mo n bawi
- Oun ni mo feran ju lo
- Awon ni o na mi
- Iwo ni mo n ki
- A le seda oro miiran lara oro aropo afarajoruko nipa lilo mofiimu “ti” ati “afi”. Apeere ;
- Ti + emi = temi
- Ati + eyin = ateyin
- Afi + awon = afawon
Akiyesi: ipaje faweli ni o waye ninu apeere oke yii
Igbelewon:
- Ko itumo oro aropo afarajoruko
- Meloo ni oro aropo afarajoruko ede Yoruba? Ya ate re.
- Ko abuda oro aropo afarajoruko
Ise asetilewa:
Ko apeere oro aropo afarajoruko marun-un ki o si fi seda oro oruko ninu gbolohun.
Yoruba lesson note for Secondary School – Edudelight.com
EKA ISE: ASA
ORI ORO: OWO YIYA
Awon agba a maa powe pe “owo ni bi oun ko ba si nile, ki enikeni ma dabaa leyin oun” . Owo se Pataki ninu igbesi aye eda. Owo ni a fi n jeun,oun ni a fi n raso,owo ni a fi n rale,kole,owo ni a fi n fe aya,owo ni a fi n to omo.koda, owo ni a fi n sin oku agba ni ile Yoruba. Idi niyi ti awon Yoruba fi n so pe “ ko si ohun ti eniyan le se leyin owo “
Ko si eni ti oda owo ki n da, bi oda owo ba si da eniyan ti o sip on dandan fun iru eni bee lati lo owo si nnkan kan, ko si ohun ti o le se ju ki o ya owo lo lati fi bo bukata naa.owo yiya maa n bo asiri sugbon airi owo da pada fun olowo je okan lara aleebu owo yiya ni ile Yoruba.
AWON OHUN TI O LE SUN ENIYAN YA OWO
- Inawo ojiji bii isinku baba tabi iya eni, isinku ana eni
- Igbeyawo
- Aisan
- Oran dida
- Oye didu
ORISI ONA TI A N GBA SAN OWO ELE PADA
- Fifi ara eni, omo ati ohun ini sofa : Ni aye atijo eni ti o bay a owo pupo ni lati maa fi ise sise loko olowo re san ele lori owo to baya. Eni ti o ya owo ti o si n lo sise sin oloko ni a n pe ni “iwofa”. Ise ti iwofa yii n se sin olowo re ni a n pe ni “ Egba tabi ogba sinsin”. Eto yiya ni lowo lon yii ni a n pe ni “iwofa yiya”.
Eni ti o ya owo le fi omo to bi tabi aburo re sodo olowo lati maa sise sin in dipo ara re lati san ele ori owo to ya. Iru igbese bayii ni a n pe ni “fifi omo sofa”. Iru omo bee ni a n pe ni “omode iwofa”.ojo ti iwofa ba san owo ti o je pada ni yoo to bo lowo olowo,ojo naa ni o di ominira patapata lowo olowo ele.
- Fifi oko sofa : Eni ti o ba ni oko yala oko koko, obi, eyin, abbl le la oko bee si meji ki o si fi apa kan re yawo. Ire apa kan oko yii yoo je ti eni ti o ya ni lowo, eyi je ele ori owo ti o ya oloko. Ire oko apa keji ni oloko yoo ti ri owo ti yoo fi san owo ti o ya pada.o si di igba ti o ba san owo yii tan ki o to gba oko re pada lowo olowo.
Igbelewon:
- Salaye asa owo yiya ni ile Yoruba
- Ko awon ohun ti o le sun eniyan ya owo ni ile Yoruba
- Salaye orisi ona ti a n gba san owo ele pada ni ile Yoruba
Ise asetilewa:
- Salaye ona meta ti eniyan le gba ya owo laye atijo.
EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: EWI ALOHUN GEGE BI ORISUN IRONU YORUBA
ESE IFA
Ese ifa ni amu fun ogbon ati oye awon Yoruba nitori Orunmila ti o je orisa awon onifa ni a n ki bayii;
“Akere finu sogbon
Eleri ipin
Akoniloro bi iyekan eni”
Ese ifa ti wa lati igba iwase ,o ku fun oniruuru akiyesi ati iriri,oun ni orisa amonimola. Bi nnkan ba sir u eniyan loju, ifa ni won yoo bere lowo re.
Apeere ESE ifa lati inu odu iwori oyeku;
“Igbo etile tountegbin
Adapo owo tountiya
Iwo o ju mi
Emi o ju o
Lara ile eni fi I fojudi ni “
Alaye: Ese- ifa yii pe akiyesi awon Yoruba si igbo ti o sun mo ile, awon obun a maa da oniruuru idoti si ibe bee ni won yoo ma yagbe sii pelu. Ewi yii tun se atenumo re pe , owo ajosepo laaarin eni meji tabi ju bee lo iya ayi iwosi lo maa n jasi. O tesiwaju pe, ilara ati owu jije maa n waye laaarin alabagbe nipa bee ainfin yoo wa. Gbogbo akiyesi yii kun fun ironu ati imo ijinle nipa ohun ti o n sele ni ayika wa.
Igbelewon:
- Salayeewi ese ifa gege bi okan lara ewi alohun yoruba
- Ko apeere ese ifa kan pelu alaye re
Ise asetilewa:
N je o ni igbagbo pe oro ogbon maa n jeyo ninu ese ifa?ko apeere ese ifa kan lati fi idi oro re mule
OSE KEJE
EKA ISE: EDE
ORI ORO : ITUPALE GBOLOHUN ONIPON – ON – NA
Pon- on – na ni ki oro tabi ifo ni ju itumo kan lo.
Pupo awon oro tabi apola inu ede Yoruba ni o ni ju itumo kan lo. Awon oro wonyi le je oro orukooro ise tabi akanlo ede. Apeere;
Oro oruko onipon –na
- Tinu : Tinu niyi
Itumo: o le je;
(a)oruko eniyan
( b)nnkan ti o wa ni inu bii; ifun,eje, omi, abbl
- Odi : mo ri odi kan ni ana
Itumo : o le je ;
(a) Eniyan ti ko le soro
(b) Ogiri ti a mo yi ilu ka
(d)odidi paadi eyin
- Ayo : ayo ko si nibe mo
Itumo 😮 le je ;
(a)Oruko eniyan, pe ko si nibe mo
(b)Idunnu, eyi tunmo sip e ko si ayo tabi idunnu ninu ile naa
Oro ise onipon – na
- Pa : awa ko ni pa atewo
Itumo : (a) Awa ko ni pa owo si orin naa
(b) Awa ko ni pa eni ti n je Atewo
- Ta : won ta aso
Itumo : (a) ki a na aso sa si ori okun
(b) ki eniyan gbe aso fun eniyan kan ki o si gba owo re
- Gun : o ti gun
Itumo: o le je;
- Pe nnkann ti gun pe ko kuru tabi kere mo
- Ki ewure tabi eranko miiran sese ni oyun
AKANLO EDE ONI-PON-NA
Akanlo Ede le ni ju itumo kan lo, itumo bee le je itumo ijinle tabi gberefu (lerefe). Apeere;
- Oba waja
Itumo: (a) oba ilu ku
( b) oba ilu wo inu orile ile
- Eru agba ni
Itumo: (a) isoro to je pe agbalagba ni o le yanju re
( b ) Eru ti omode ko le da ru si ori
- Anike ti wo ileya
Itumo : (a) O ti dagba
(b) O ti wo inu ileya
(d) O ti to pa eran odun ileya
(e) O ti to loko
GBOLOHUN ONIPON-ON-NA
Awon gbolohun miiran ni ju itumo kan lo ti a ba pe won. Apeere;
- Iya aje naa ti de
Itumo: (a) iya ti o bi iya aje ti de
- Iya ti o je aje gan – an lo de
- Omo Akin
Itumo : (a) omo ti Akin bi
(b) Akinkanju omo
(d)omo ise Akin
- Ayo wun mi
Itumo : (a) mo feran eni to n je Ayo
(b)mo fe ni ayo tabi idunnu
Igbelewon :
- Fun pon-on-na ni oriki
- Ko apeere meji meji lori
- Oro ise oni-pon-on-na
- Akanlo ede oni-pon-on-na
d.Gbolohun oni-pon-on-na
Ise asetilewa:
Se ise sise lori akole ise yii niinu iwe ilewo Yoruba Akayege.ibeere kin- in -ni de ikarun –un (1-5)
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ONA TI A N GBA FI SAN GBESE
- Ifibiya : Eyi je ona ti a n gba fi gba gbeselowo onigbese to ko lati san owo pada ni worowo.olowo yoo mu suuru patapata,yoo si dabi eni pe o ti gbagbe owo naa sowo onigbese sugbon yoo maa so onigbese kaakiri gbogbo ibi ti o ba ti n taja,bi olowo bam o ibe,yoo ra oja ti o kaju iye owo ti onigbese je e, yoo si yise pada. Bi onigbese ba pe olowo yii pad ape ko I ti I san owo oja,olowo yoo wa so fun un pe ki o fi owo to je oun di owo oja re.
- Emu : eyi je ona ti a n gba gbese ti o bap o die. Olowo yoo lo be awon elemu –un (agbowo ipa) lati ba oun gba gbese lowo onigbese. Awon elemu yoo lo fi ipa gba ohun ini onigbese fun olowo titi onigbese yoo fi ri owo ti o je san. Bi onigbese ko ba tete wa owo naa san fun olowo, olowo yoo ta nnkan ini onigbese bee yoo si fi di owo re. Eyi ti o ba si ku lara owo bee ni olowo yoo fun awon elemu –un gege bi owo ise won.
- Ologo : Eni ti o ya ni lowo yoo ran ologo lo si ile onigbese lati lo gba owo naa ni tipatipa. Awon abirun tabi alarun bi I; adete,ati awon ti o ni egbo nla yanmokan lara ni o saba maa n se ise ologo. Bakan naa, awon tie nu won mu berebere,ti o mo eniyan bu daadaa,ti o si le fi ajigbese se esin laaarin awujo naa maa n se ise ologo. Ni aye atijo nigba ti wahala olgo bas u awon ara ile onigbese, won le da owo naa jo lati san gbese naa. Lara owo ti ologo ba gba fun olowo ni yoo ti yo tire gege bi oya ise re.
- Eda ogboni : opa ogboni ni edan. A kii dede fi edan yii ranse eni ti kii se omo egbe ogboni ti ko ba ni idi Pataki gege bi I igba ti a ba fe lo o lati fi gba gbese. Gbese ti o bap o pupo ni a maa n lo edan ogboni lati gba. Ako edan ogboni ni a n gbe lo si ile onigbese, enu ona abawole ni won maa n ri I mo. Eni ti a je ni gbese ni yoo lo baa won ogboni ninu ilu pe ki won ba oun gba gbese ti enikan je oun. Ti onigbese ati awon ara ile re ba ko lati san gbese naa ni kia kia, awon ogboni yoo gbe eniyan kan lara awon omo agbo ile re ta gege bi eru lati fi san owo ti ajigbese je.
Bi onigbese ba si ku lai san gbese ti o je, won ki I sin iru oku bee bi oku eniyan gidi, won yoo gbe oku re ko igi nla,ibe ni yoo ra si ti awon eye igun yoo fi je eran ara re tan. Gbese jije lai san ki I se iwa omoluabi raras, bi o ti le je pe ko si eni ti oda owo ki I da, sibe dandan ni fun eni ti o bay a owo ki o da a pada gege bi I adehun nitori ojo miiran. Lode – oni, a n ya owo ni ile ifowo – pamo – si , egbe ajeseku ati lowo ore gbogbo.
Igbelewon:
- Ko ona merin ti a n gba san gbese laye atijo
- Salaye awon ona wonyi ni kikun
Ise aetilewa:
Lode oni, salaye ona meji pere ti a le fi gba gbese
EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: EWI ALOHUN GEGE BI ORISUN AGBARA ATI IMO IJINLE
YORUBA
Ewi alohun ni awon ewi ti a jogun lati enu awon baba nla wa.
O je okan Lara litireso ti awon baba nla wa maa n lo lati iwase.
Agbara ti o ya ni lenu ati imo ijinle n be lowo awon Yoruba, idi niyi ti a fi n pe won lolopolo pipe ati alarojinle eda.
Apeere awon ewi alohun ti o fi idi otito mule pe awon Yoruba je alarojinle ati olopolo pipe niyi;
- OFO
Ofo je oro ti a n so tabi fo jade ti a fi n segbe leyin oogon tabi ti a n pe lati mu ero okan wa se.
Apeere ofo awure;
“Itun lo ni ke e fohun rere tun mi se
Ifa lo ni kie e fohun rere fa mi
Abeere lo ni ke e fohun rere beere mi
Tigi tope ni I saanu afomo
Omo araye e maa saanu emi lagbaja
Omo lagbaja loni o “
Itumo ofo yii ni pe, nibi ki bi ti o ba n de ki awon eniyan maa fi ohun rere le e lowo
- AYAJO
Omo iya ofo ni ayajo sugbon inu ese ifa ni oun ti maa n je jade. Oro enu lasan ni ko nilo oogun rara.
Apeere ayajo ti a fi n da inu rerun duro;
“ O-dorita-meta pete isale
O-dorita-meta pero orun oyela
Eyin le yo Olugbon asiri
Ti Oduduwa pa enu re mo
A-ka-woroko-ori-idodo
A-na-le-ori-iwo
Ojo lo de lo mu aganna alaganna gun
Kuro ninu aganna
Ki o wa ibomiiran lo”
- OGEDE
Ohun enu bii ti ayajo ni ogede sugbon ohun enu ti o ni agbara ju ohun enu lo ni. Enikeni ti o ba fe pe ogede gbodo ni ohun ti yoo koko se tabi je gege bii ero ki o to le pe e rara bee ni o gbodo ni ohun ti yoo sare je tabi to la ti o ba tip e e tan ki inira ma ba de ba a. eni ti yoo gbo ogede naa gbodo lo ero tabi ki eni ti yoo pe ogede ti se ohun ti ko ni je ki o se onitoun ba kan.
Igbelewon:
- Kin ni ewi alohun?
- salaye ewi Yoruba meji ti o fi idi re mule pe Yoruba je alarojinle ati olopolo pipe
Ise asetilewa: Ni iwoye tire n je awon ewi alohun wonyi si nje bi ti atijo? Salaye ni kikun
OSE KEJO
EKA ISE: EDE
ORI ORO: AROKO ASARINYANJIYAN
Aroko asarinyanjiyan ni aroko eyi wun mi ko wun o
Abuda aroko asariyanjiyan
- Iha meji ni aroko yii maa n ni,iha mejeeji yii ni a si gbodo ye wo finni-finni
- Iha ti a fara mo ni a o soro le lori ni ikadi aroko lekun rere lati fi aridaju han pe loooto ni a fara mo apa kan ninu ori oro aroko naa.
Apeere aroko asariyanjiyan:
OMO DARA JU OWO LO
- Ohun akoko ni ifaara
- Sisoro lori iha mejeeji : (a) omo – anfaani omo ati aleebu
(b)Owo – anfaani ati aleebu
- Ikadi aroko – eyi ni fifi ara mo iha kan ti o wun ni ninu ori oro.
Kiko aroko naa lekun-un rere
OMO DARA JU OWO LO
‘Omo niyi
Omo leye………………..
Bee ni;
‘Owo ni ti oun ko ba si nile,
Ki enikeni ma dabaa kankan leyin oun’
Awon ipede yii fi ipo omo ati owo han ni awujo awa eda. Bi o tile je pe ko se maa ni ni awon mejeeji sibe a ko le sai mop e iha kan se koko ju ekeji lo
Ohun idunnu ati ayo ni omo je. Idi niyi ti alaboyun bar u u re, ti o si so layo, ohun Ayo nla lo je fun ebi ati ara. Won a si mule poti, won a fi ona roka ni ojo ikomojade.
Bee ni aro ni omo je. Oun ni yoo gbeyin obi ni ojo ola. Yoruba Gbagbo pe obi ti ko ba fi omo saye, o wa ile aye asn nitori pe, omo eni lo n gbe ni de ibi giga, oun si ni aso eni.
Ni idakeji, wahala obi ko kere lori omo, lati kekere ni awon obi yoo ti maa nawo nara lori omo sugbo aimoye omo ni kii roju raye toju awon obi won lojo ogbo. Awon omo miiran a si darapomo egbe – kegbe ti won a si tibe ba oruko ebi won je.
Idi niyi ti awon omoran Kan fi so pe “owo dara ju omo lo” nitori ki ni anfaani omo lai si owo? Anfaani owo ko kere rara. Ko si ohun ti eniyan fe se ti ko nilo owo.
Owo a maa gbe eniyan ga ni awujo, owo a maa fun eniyan ni aponle nibi gbogbo. Koda, bi oro kan ba kan olowo ninu ebi, won a ni ki o de ki won to bere ipade.
Sugbon kii dara ko ma ku si ibi kan. Owo a maa fa igberaga ni ipo agba. Yoruba bo won ni “igberaga ni I saaju iparun” bakan naa, ife owo le mu ki eniyan padanu ijoba orun nitori pe opo olowo ni ki I raye sin olorun bo ti to ati bi o ti ye. Oniruuru iwa ibaje bi i; adigunjale, fifi omo soogun owo ati bee bee lo ni awon enyan Gbagbo pe o kun owo awon olowo nitori ife owo aniju
Ni okodoro, owo ki i to olowo.ti a ba si fi oju inu inu wo o daadaa,a o o ri I pe oto lowo,oto lomo. Ojo ti olowo ba ku ni owo re ku, ojo ti olowo ba ku ni ola re wooku, gbogbo ohun ini olowo ti ko bi omo a di teni eleni. Awon agba bo won ni “ina ku o fi eeru boju, ogede ku o fi omo re ropo”.
Idi niyi ti mo fi fara mo o wi pe omo dara ju owo lo.
Igbelewon:
- Fun aroko asariyanjiyan loriki
- Ko abuda aroko asariyanjiyan meji
- Ko apeere ori oro aroko asariyanjiyan meta
Ise asetilewa:
Ko aroko lori “Ise owo dara ju eto eko lo”
Yoruba lesson note for Secondary School – Edudelight.com
OSE KESAN-AN
EKA ISE : ASA
ORI ORO : ASA ISINKU NI ILE YORUBA
Isinku ni eye ikeyin ti a se fun oku logan ti o ku titi di akoko ti a fi sin in
Yoruba gbagbo pe “eni sinku lo pale oku mo, eni sunkun ariwo lasan lo pa”
Igbese isinku ni ile Yoruba
- Itufo : eyi ni kikede iku oloogbe fun awon ebi ,ana ati gbogbo eniyan. Ilu liu, ariwo, ekun sisun, ibon yinyin ni a fi n tufo oku.
- Ile oku gbigbe : awon ana tabi omo okunrin ile oku ni yoo gbe ile iwon ese mefa lati sin oku
- Oku wiwe : won ni lati fa irun ori oku ti o ba je okunrin, won a si di irun ori oku ti o ba je obinrin. Gbogbo eekanna owo ati ese oku ni won yoo ge leyin naa ni won yoo fi ose ati kanin-kain pelu omi to loworo we e. leyin eyi ni won yoo wo aso to dara fun oku.
- Oku tite : inu yara tabi odede ti won se losoo ni won n te oku si ni ori ibusun pelu aso funfun ati lofinda olooorun bee ni won yoo fi owu di iho imu ati eti re mejeeji. Ni asiko yii, awon obinrin ile yoo maa ki I ni mesa-an mewaa.
- Alejo sise : Awon omo ati ebi oku yoo peae jije ati mimu fun awon okunrin ile, awon ana ti o gbele oku ati gbogbo alejo patapata.
- Isinku : eyi ni ayeye “fifi erupe fun erupe”. Won yoo gbe oku sinu posi pelu oniruuru nnkan bii; owo, ounje,ileke,aso,bata, opa itile ati nnkan meremere miiran lati lo ni iri ajo naa nitori Yoruba Gbagbo pe iye wa leyin iku ati pe irin ajo ni oku n rin lo si orun. Ni geere ti won ba ti gbe oku sinu koto, awon omo oloku ati ebi re yoo bu eeru si oku naa lara.
Igbelewon:
- Kin ni asa isinku?
- Ko igbese asa isinku mefa pelu alaye kikun
Ise asetilewa:
Salaye bi a se n se isinku ni ilana esin re.
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ASA ISINKU NI ILE YORUBA – OKU ABAMI
Awon iku ti o ba ni leru ti o si buru ju ni iku abami ni ile Yoruba.
Iku yii buru to bee gee to fi je pe Yoruba ki I sokun won, ibaa je oku omode tabi ti agbalagba nitori pe ohun ti o sele ti koja ekun.
Oniruuru oku abami
- Oku oba
- Oku alaboyun
- Oku abuke
- Oku adete
- Oku aro
- Oku afin
- Oku eni to ku si odo
- Oku eni ti igi ya lu
- Oku eni ti sango pa
- Oku eni ti o pokunso
- Oku oba : bi oba ba ku ohun ti a naa n so nip e “ oba waja “ tabi “ ile baje” . ilu gbedu, koso ati fere eyin erin ni a fi n tufo oku oba ni afemojumo laafin. Awon olorisa ati ogboni yoo sim aa se oniruuru etutu ni afin oba,opolopo nnkan oro ni won yoo gba lowo Daodu oba. Akoko etutu yii ni as gbo pewon yoo yo okan oba, ti won a si yan an gbe de oba miiran ti yoo joba,ni gba ti won ba si n se etutu oba tunun,won yoo fun un ni okan oba to awja,won a si bi I lere pe ki lo n je,yoo dahun pe “oun n joba”. Abobaku Alaafin yoo ma jo kiri ile ati ilu pe oun ti setan lati ba oluwa oun ku. Ki I se oun nikan , opo eru, Aayo oba, opo ayaba ati Aremo oba ni yoo maa jo kaakiri ilu pelu lati fi iyanda won han gbogbo ilu lati ku pelu oba. Leyin eyi ni inawo oku fun ogberi yoo bere.
- Oku alaboyun: eyi ni oku ti o buru ju lo.Yoruba a ni eni ti o ku yi I’subu lu owo’ tabi o lo ni ‘ilokulo’. Gbara rti o ba ti ku enikeni ko gbodo wo inu ile naa mo titi ti awon oloro yoo fi de. Ko si ohun tie nu nje ti awon oloro ko ni gba lowo oko ati ebi oloku naa. Eyi le mu ki oko sa kuro ninu ilu patapata nitori pe inawo kekere ko ni isinku naa. Awon aworo yoo gba gbogbo ohun ini oku patapata lai ku abere , awon oloro yii pelu yoo se isinku oku yii pelu omo inu re lotooto. Won yoo sim aa kede kiri ilu pe enikeni ti o ba je oku lowo tabi ohunkohun ki o da pada ki won to sin in bi oun naa ko ba fe ku iru iku bayii. Igbo oro ni won maa n sin irufe oku bee si ni ile Yoruba.
- Oku abuke : Yoruba Gbagbo pe o wu Orunmila (Obatala) lati moa buke bee ati pe ‘eni orisa’ ni won maa n pe won.igale awon olrisa ni a maa n sin iru oku bee si i. opolopo ohun etutu ni awon olorisa yoo si gba lowo awon ebi oku naa.
- Oku afin : abore ti o ba fe se etutu fun oku afin ko gbodo je iyo, ko gbodo sun mo obinrin, ko si gbodo so fun eni Kankan titi etutu naa yoo fi pari
Igbelewon:
- Fun oku abami loriki
- Ko oniruuru oku abami meje
- Salaye meji pere ninu awon oku abami wonyi
Ise asetilewa:
Sango je okan lara awon orisa ile Yoruba ti o si ni I se pelu ara ati ina.kin ni awon ohun ti o le fa ti sango fi le pa eniyan kan ni ile Yoruba?
OSE KEWAA
EKA ISE: EDE
ORI ORO: AROKO – LETA KIKO
Leta kiko je ona ti a n gba gbe ero okan wa kale lori pepa ranse si elomiiran.
Isori leta
- Leta gbefe
- Leta aigbefe
LETA GBEFE
Leta gbefe nil eta ti a maa n ko si eni ti o sunmo wa; o le je molebi, ore, tabi alajose.
Leta gbefe fi aaye gba eniyan lati fi ero inu re han elomiiran. O le je baba, iya, egbo, aburo, ore ati ojulumo eni gbogbo.
Igbese kiko leta gbefe
- Adiresi akoleta : Apa otun ni oke tente ni adireesi akoleta maa n wa. Nonba ojule, opopona tabi apoti ile ifiwe ranse si (p.o. Box) , oruko ilu ati ipinle eni ti a n ko leta si ni yoo wa ninu adireesi yii.
- Deeti : ojo, osu, ati odun ti akoleta n kowe re yoo wa ninu adireesi yii.
- Ikini ibere : apa osin ni ibere ila ti o tele deeti ni a n ko eyi si pelu ami idanuduro die ni ipari re.
- Koko leta : eredi ti akoleta fi n ko leta re ni yoo so di mimo ninu ipin afo yii.
- Ipari/ikadi leta : owo otun ni akoleta yoo sun owo si ni ori pepa, oruko akoleta nikan ni yoo han ni opin leta yii pelu ami idanuduro die.
Igbelewon:
- Kin ni leta kiko?
- Ko orisi leta meji
- Salaye okookan ni kikun
- Ko igbese leta kiko marun-un pelu alaye kikun
Ise asetilewa:
Ko leta si ore re nipa awon aseyori ti o ni lenu eto eko re ni saa yii.
EKA ISE: ASA
ORI ORO: ASA ISINKU – OKU ABAMI
- Oku eni ti igi yalu pa :eedi lo maa n mu ki igi ya lu eniyan pa, ki I se oju lasan, ija ogun to le ni. Ni geere ti isele yii ba sele ni awon molebi oku yoo ti ranse pea won oloro. Gbogbo dukia oku patapata ni won yoo gba, won a si se etutu nidi igi ti o ya pa iru oku bee,idi igi naa ni won yoo si si in si nitori pe won ko gbodo gbe iru oku bee wo ilu.
- Oku eni ti o pokunso : bi eniyan ba pokunso, ki ba se lori igi tabiaja ilea won molebi yoo ra ohun etutu pelu owo repete ni won yoo ko fun awon oloro. Awon oloro yoo se etutu, leyin naa ni won yoo ge okun ti oku naa fi pokunso . Idi igi naa ni won maa n sin iru oku bee si.gbogbo dukia oku yii ni awon molebi yoo ko fun awon oloro.
- Oku odo: agba inawo ni oku eni to ku si odo.inawo pajawiri yii klo ni je ki awon molebi oku ranti ekun nitori pe gbogbo ohun tie nu n je ni awon oloro yoo gba lowo won lati fi se etutu oku fun orisa odo (yemoja). Eti odo naa ni won yoo sin iru oku bee si nitori eni ku si odo ti di ‘olu – odo ‘Omo eni ti o ku si odo ko gbodo mo oju oori baba tabi iya re ti isele yii sele si laelae.
Igbelewon:
- Fun asa isinku loriki
- Ko oku abami marun- un ki o si salaye meji pere
Ise asetilewa:
Gege bi I iwoye tire, irufe oku wo lo bani leru ju? salaye
EKA ISE: LITIRESO
ORI ORO: ITUPALE ASAYAN IWE EWI TI AJO WAEC/NECO YAN FUN TAAMU YII.