Lesson Note Yoruba SS1 Second Term

Yoruba lesson notes for SS1 Second Term – Edudelight.com

SECOND TERM

YORUBA LANGUAGE   SS ONE

ETO ISE FUN SAA KEJI

Ose kin-in-ni                             Ede-Atunyewo awon isori oro ninu ede Yoruba

                                                     Asa:Elegbejegbe tabi iro-siro

                                                     Litireso: Itupale iwe aseyan ti an ka

Osa keji                                      Ede-Awon isori gbolohun ede Yoruba gege bi ihun

                                                     Asa: Asa iranra-eni lowo

                                                     Litireso: kika iwe litireso ti ijoba yan

Ose keta                                     Awon isori gbolohun Yoruba gege gi ise won

                                                     Asa: Itesiwaju ninu asa iranra-eni lowo

                                                     Litireso : kike iwe litireso ti ijoba yan

Ose kerin                                    Ede-Aroko asapejuwe (ilana)

                                                     Asa: oge sise(1)

                                                     Litireso: kika iwe litireso ti ijoba yan

Ose karun-un                             Ede- Akanlo ede

                                                     Asa : oge sise (2)

                                                     Litireso : kika iwe litireso ti ijoba yan

Ose kefa                                     Ede- sise aayan ogbufo

                                                     Asa: Igbeyawo ibile

                                                     Litireso: Kika we litireso ti ijoba yan

Ose keje                                     Ede-sise aayan ogbufo

                                                     Asa: igbeyawo ni ile Yoruba, orisi igbeyawo ti o wa

                                                     Litireso: kika iwe litireso apileko ti ijoba  yan

Ose kejo                                     Ede-onka ede Yoruba ookan de egbaa (1-2000)

                                                     Asa: Asa igbeyawo

                                                     Litireso: kika iwe litireso ti ijoba yan

Ose kesan                                   Ede- Atunye eko lori

                                                     Asa: Oyun ninu, itoju ati omo bibi

                                                     Litireso : Itan oloro geere bii; orisunn itan ati asa Yoruba

Ose kewaa                                  Ede- Aroko asotan oniriyin

                                                     Asa: Asa isomoloruko

                                                     Litireso: Alo apamo ati apagbe

Ose kokonla                              agbeyawo ise saa keji

Ose kejila                                   Idanwo Ipari saa keji

Ose kin-in-ni

Akole ise: Ede- Atunyewo

Isori oro ninu ede Yoruba

Isori oro ninu ede Yoruba ni wonyii

 1. Oro-oruko
 2. Oro Aropo oruko
 3. Oro Aropo Afarajooruko
 4. Oro Eyan / Apejuwe
 5. Oro Ise
 6. Oro Aponle
 7. Oro Atokun
 8. Oro Asopo

Oro-oruko: Eyi ni awon oro ti won le da duro ni ipo Oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun.

Ipo meta ni oro oruko le ti jeyo ninu gbolohun.  Awon ni ;

 1. Ipo Oluwa :-  Eyi ni oro oruko ti o jeyo ni ibere gbolohun tabi ti o je oluse isele inu gbolohun.  Apeere ;

Sola lo si iwo

Ade jeun yo

Alaafia to oyo

 • Ipo Abo :-  Eyi ni olu faragba nnkan ti oluwa se ninu gbolohun.  Aarin tabi ipari gbolohun ni o maa n wa.  Apeere ;

Oluko ra oko ni ona

Jide gun iyan

 • Ipo Eyan :-  Ti oro oruko meji ba tele ara ninu apola oruko, oro oruko keji ni yoo yan oro oruko kin-in-ni.  Apeere ;

Olumide oluko ti de

Iwe iroyin dara lati maa ka

Eja alaran-an ni mo fe ra.

Oro oropo-oruko :-  Orisi ipo meta ni oro oropo-oruko ti le je yo ninu ihun gbolohun ede Yoruba.

 1. Ipo Oluwa :-

Eni                  Eyo                 Opo

Kini                mo                   A

Keji                 O                     E

Keta                O                     Won

 1. O le je yo saaju oro-ise nipo oluwa.  Apeere ;

Eni                  Eyo                 Opo

Kiini               Mo sun           A sun

Keji                 O sun              E sun

Keta                O sun              Won sun

 1. O le jao saaju erun ‘n’ ninu apola ise.  Apeere;

Eni                  Eyo                 OPo

Kiini               Mo n sun        A n sun

Keji                 O n sun           E n sun

Keta                O n sun           Won n sun

 1. O le je yo saaju awon wunren bii ko/o ki, iba, ibaa.  Sugbon oro aropo eniketa ko le wo iru ihun yii.  Apeere;

Eni                  Eyo                 Opo

Kiini               N o sun          A o sun

Keji                 o ko sun         E baa sun

Keta

 • Ipo abo

Eni                  Eyo                                                     Opo

Kiini               Mi                                                       Wa

Keji                 O/e                                                      Yin

Keta                Afagin faweli to gbeyin oro-ise     won

Akiyesi:-       

 1. Ti oro-aropo oruko ba wa leyin oro ise olohun oke, ohun aarin ni oro aropo oruko ba yoo ni.  Apeere;

Eni                  Eyo                 Opo

Kiini               O ki mi           O ki wa

Keji                 O ki o/e          O ki yan

Keta                O ki  I             O ki won

 1. Ti oro aropo oruko ba wa leyin oro ise olohun aarin, ohun oke ni oro aropo oruko bee  yoo ni.  Apeere;

Eni                  Eyo                 Opo

Kiini               O bi mi           o bi wa

Keji                 o bi ole                       o bi yin

Keta                o bi i               o bi won

 1. Ti oro aropo oruko ba wa leyin oro ise olohun isale, ohun oke ni oro arop oruko bee yoo ni.  Apeere;

Eni                  Eyo                 Opo

Kiini               o ti mi             o ti wa

Keji                 o ti o/e                        o ti yin

Keta                o ti I                o ti won

 • Ipo eyan

Eni                  Eyo                 Opo

Kiini               mi                    wa

Keji                 re                     yin

Keta                re                     won

Apeere, 

Eni                  eyo                  opo

Kiini               ile mi niyi      ile wa niyi

Keji                 ile re niyi       ile yin niyi

Keta                ile re niyi       ile won niyi

 Oro-oruko Afarajoruko:-  Eyi je oro ti a n lo dipo oro-oruko.  Awon ni,

            Eni                  Eyo                 Opo

            Kiini               Emi                 Ewa

            Keji                 Iwo                  Eyin

            Keta                Oun                 Awon

Oro-eyan:-  Eyi ni awon oro ti won n yan oro-oruko ninu apole-oruko

Orisi oro-eyan

 1. Eyan Asapejuwe:-  O maa n sapejuwe oro-oruko ni ona ti yoo fi ye ni yekeyeke.  Apeere;

Oruko rere wu mi

Ounje kekere ko yo mi

Eja yiyan dun n mu gaari

ii.          Eyan Ajoruko :- Eyi ni oro oruko tabi oropo-oruko ti a n lo lati yan oro-oruko miran.  Apeere ;

Aja ode pa okete

Adisa tisa ra oko

iii.          Eyan Asafihan :- O maa n toka si ohun ti a n soro nipa re gan-an.  Apeere ;

(a)       Oro ohun ti su mi

(b)       Ise wonyi le ju fun wa

 1. Eyan asonka :-  O maa n toka si iye ninu gbolohun.  Apeere ;
 2. Ile meta ni oga ni
 3. Iyawo kan ni baba mi fe
 4. Eyan alawe gbolohun asapejuwe :-  O maa n fi itumo kun oro oroko ninu gbolohun.  “ti » ni wunren atoka eyan yii.  Apeere ;
 5. Aso ti a ri ni oja ko dara to
 6. Ile ti o n san fun wara ati fun oyin ni ile Naijiria

Oro ise:  Eyi ni koko fonran to n toke isele tabi nnkan ti oluwa se ninu gbolohun.  Apeere orisi oro ise.

            Bola lo

 1. Kunle jeun    
 2. Mo je akara

Kike mu omi            

 • Olorun wa
Ona ise Asodidi gbolohun    

Moji sun

 • Wa, jade, joko           –          
 • Mo ra bata

Bola ke

 • O je iyan yo

Ola fo ka eso agbalumo

 • Mo pa ile mo (pamo)

Olu ba aga je (baje)

gb)      mo subu lule (subu)

            mo ranti itan ilu mi (ranti)

Igbelewon :-

 1. Ko isori oro yoruba mejo
 2. Salaye pelu apeere meji meji ni kukuru

Ise Asetilewa :-

ko apeere meji meji fun isori oro kookan ti a se ayewo re yii

ASA:-  Asa Elegbejegbe tabi iro-siro

Eyi ni awon eniyanti ojo ori won baara wonmu.Bibeli wi pe, nigba ti mo wa ni ewe, emi a maa huwa bi ewe, emi o maa soro bi ewe, sugbon nigba ti mo di okunrin tan mo fi iwa ewe sile”.  Oro inu bibeli yii fi idi re mule pe otooto ni ihuwasi elegbejegbe to wa.

Ojo ori ni eda eniyan kookan fi n pin eniyan si elegbejegbe tabi iro isiro .Yoruba bo won ni “egbe eye leye n fo to, egbe eja ni eja sii we to”.  Iwa ti awon iro kan ba n hu ni gbogbo awon to ba wa ninu iro naa yoo maa hu”

Pipin Eda Eniyan Si Elegbejegbe/Iro Siro

 1. Omo omu, omo owo, ikoko, arobo ati omo irinse ( omo oojo titi de omo odun meta)
 2. Majesin (omo odun meta si marun-un)
 3. Omode (omo odun mefa si metala)
 4. Agunbaniro (odun merinla si ogun odun)
 5. Gende/igiripa (odun mokanlelogun titi de ogoji odun)
 6. Agba (ogoji odun si aadorin odun)
 7. Arungbo (aadorin odun lo soke)

Ede Ti Irosiro Maa N Lo

Ede abykun ni ki iro ti o kere lo iwo fun agbalagba.  Ede bii; e, eyin, yin, won ni iro ti o kere ni lati lo fun iro ti o dagba ju ni lo.  Bi o ti le je pe awon eya miran ta pa si eyi.  Ede arifin ko ye omoluabi gege bi asa ajumolo ile Yoruba.

Iranlowo Ti Iro Siro N Se Fun Ara Won

 1. Awon ogunbaniro maa n ba ara won se aaro lati fi se ise oko
 2. Won maa n ran ara won lowo nipa oro to ba jemo owo nipa ajo tabi esusu
 3. Ba kan naa, awon agunbaniro, igiripe ati awon agbe lokunrin lobinrin laye atijo maa n be ara won ni owe lati fi se ise ti won ba fe se.

Igbelewon:-

 1. Salaye elegbejegbe tabi iro siro
 2. Pin ede eniyan si elegbejegbe
 3. Iranlowo wo ni iro sire lo se fun ara won?
 4. Irufe ede wo ni o ye ki iro siro maa lo fun ara won?

Ise Asetilewa:Salaye ojuse awon agunbaniro ninu idagbasoke orile ede Nigeria

LITRESO:-  Itupale iwe asayan ti a n ka.

                        OSE kEJI

Akole Ise:- Ede:-  Awon isori gbolohun Ede Yoruba Gege bi Ihun

Gbolohun ni afo ti o kun, to si ni ise to n se nibikibi ti won be ti je jade.

Gbolohun Abode/Eleyo oro-ise

Eyi ni gbolohun ti ko ni ju oro-ise kon lo

Gbolohun abode kii gun, gbolohun inu re si gbodo je oro ise kiku.  Apeere ;

Dosumu mu gaari

Aduke sun

Ihun gbolohun abode/eleyo oro-ise

 1. O le je oro ise kan.  Apeere ;  lo, sun, jokoo, dide, jade, wole
 2. Oro ise kan ati oro apola.  Apeere; 
 3. Anike sun fonfon
 4. Ile ga gogoro
 5. Oluwa, oro ise ati abo.  Apeere;
 6. Ige je eba
 7. Oluko ra oko
 8. O le  je oluwa, oro ise kan, abo ati apola atokun.  Apeere
 9. Aina ru igi ni ana
 10. Ojo da ile si odo
 11. O le je oluwa, oro ise kan ati apola atokun.  Apeere ;
 12. Mo lo si oko
 13. Bab wa si ile

Gbolohun Alakanpo

Eyi ni gbolohun ti afi oro asopo kanpo mo ara won

Akanpo gbolohun eleyo oro ise meji nipa lilo oro asopo ni gbolohun alakanpo.

Awon oro asopo ti a le fi so gbolohun eleyo oro ise meji po ni wonyi; ayafi, sugbon, oun, ati, anbosi, amo, nitori, pelu, tabi, koda, boya, yale abbl.

Apeere;

 1. Yemi ke sugbon n ko gbo
 2. Tunde yoo ra aso tabi ki o ra iwe

Igbelewon:-

 1. Kin ni gbolohun?
 2. Salaye gbolohun abode ati alakanpo pelu apeere meji meji

Ise Asetilewa:-  ko apeere gbolohun abode ati gbolohun alakanpo meji meji

Asa:-  Asa Iranra-Eni Lowo I

Awon agba bo won ni « Ajeje owo kan ko gberu dori ».  Eyi tun mo si pe owo kan soso ko gberu dori.  Bee si ni « Agbajo owo la fi iso aya » a ko le fi ika eyo kan so aya.  Bi a ba pa owo po fi se nnkan tabi bi a b pa owo po fi ran ara eni lowo, oun lo le mu iroran wa.

Emi imoore se pataki ni ile Yoruba.  Awon yoruba maa n fe ki eniyan ti a se oore fun fi emi imoore han idi nyi ti won fi n s ope Eni ti ase loore ti ko dupe o dabi ki olosa ko ni leru lo sugbon    

kii se pe ki eniyan se ni loore ki o lo soo ti i.

Asiko/igba ti Yoruba n ran ara won lowo laye atijo

 1. Asiko isoro
 2. Ni gba nnkan ayo ati idunnu won a maa fun ara won lebun
 3. Won a maa ya ara won lowo ni gba ti inawo nla ba sele si enikan abbl.

Ona ti a n gba ran ara eni lowo ni ile Yoruba

Aaro:–  Awon odomokunrin ti oko won ko fi bee jina si ara won a maa be arar won ni aaro, won yoo si maa lo si oko ara won kaakari lojo Kookan.  Won kii poju.

Awon obinrin ti iro won ko ju ara li naa maa n be ara won ni aro ti o je mo ise obinrin

Aanfaani aaro

 • O maa n mu ki ise ya
 • Ise ti o ro enikan loju lati s e yoodi sise pelu irorun bi a ba da owo boo
 • O n mu ife ati irepo wa laarin ara eni
 • O n mu ki a ni igbekele ninu ara eni
 • O je ona iranra eni lowo

Owe :-  Ise ti o ba po jaburata ti enikan ko le da se funra ra bi o ti wu ki o lagbara to ni won nfi owe se. 

 • A le fi owe sa igi ti yoo ro ile
 • A le fi pa koriko tabi ewe ti yoo fi bo ile gege bu orule.

Ana eni le be ni lowe, to kunrin tobinrin tomode tagba ni a maa n be lowe.  Gege bi apeere, bi o ba je owe agiri ile mimo, awon omode ni yo pon omi, awon gende yoo sa yepe, won yoo po o lati fi mole, awon agba obinrin yoo si maa se ounje.

Ebese :-  Eyi ni ise ti ko po ti a be awon eniyan lati se ni asiko inawo repete ti n bo ni waju

Arokodoko :-  Awon odomekunrin ti won je iro ti oko won ko jina si ara won a maa sowopo ba ara won se ise loko.

Esusu :-  Awon ti won mo ara won deledele ti won tun je olotito maa n ko ara won jo laye atijo lati da esusu won yoo  seto laarin ara won iye ti eni kookan yoo maa da gege bi agbara re se mo.  Emi ti won yan gege bu oloro won ni a n pe ni olori-eleeesu ».  iye ti eniyan ba da ni yoo gba.

Ajo :-  A maa n da ajo bi igba ti a n da esusu sugbon iyato ti o wa laarin ajo ati esusu ni pe iye ti eniyan ba da ni yo ko ninu esusu sugbon ninu ajo dandan ni ki a se eyo kan ku, o le je iye ti eniyan n da lojo kan tabi leekan soso eyi ni ere eni ti n gba ajo.

Oja Awin/aradosu :-  Ti to eni ti o n ta oja lo lati gba oja lai san owo ni kiakia wopo laye atijo.  Ti tele adehun lori ojo ti a oo san owo oja pada se pataki ki oloja le tun le se iranlowo fun inu eni bee lojo miran.

San die-die/osomaalo :-  Eniyan le ra oja awin pelu adehun lati maa san owo re diedie titi yo fi san ta.  Pelu ipa/agidi ni awon ti n sun owo fi maa n gba gbese won ni aye atijo.

Igbelewon :-

 1. Salaye ase iranra-eni lowo
 2. Asiko wo lo tona lati se iranlowo fun ara won
 3. Salaye awo ona ti a le gba ran eni lowo laye atijo

Ise Asetilewa:-N je o dara lati se iranlowo lode-oni? Salaye ona marun-un ti awon akeekoo le  gba se iranlowo fun ara won lode oni

LITRESO :-  Kika iwe litreso ti ijoba yan.

OSE KETA

Akole Ise:-  Ede:- Awon isori gbolohun Yoruba gege bi ise won.

 1. Gbolohun alalaye
 2. Gbolohun ibeere
 3. Gbolohun ase
 4. Gbolohun ebe
 5. Gbolhun ayisodi

Gbolohun Alalaye:-  Eyi ni a fi n se iroyin bi isele tabi nnkan se ri fun elomiran lati gbo.  Apeere.

 1. Ebi n pa mi
 2. Tisa lo gba iwee mi

Gbolohun Ibeere :-  Eyi ni ona ti a n gba se ibeere nipa lilo atoka asebeere bii, tani, ki ni, ba wo me loo, igba loo, n je, sebi, abi abbl.  Apeere ;

 1. N je won gba ?
 2. Se Ade wa ?

Gbolohun Ase :-  Eyi ni gbolohun ti a fi n pase fun eni ti a n ba soro.

Apeere ;

 1. Dide duro
 2. E dake jeje

Gbolohun Ebe :-  A n lo gbolohun ebe lati fi bebe fun ohun kan.  Apeere;

 1. Fun mi ni omi mu
 2. Jowo maa bu mi mo

Gbolohun Ayisodi:-  Gbolohun yii ma n fihan pe isele kan ko waye.  Itumo re ni bee ko.  Awon oro, atoka gbolohun ayisodi ni; ko, kii, ko I, le. Apeere;

 1. Olu o le lo
 2. Oluko ko I ti lole
 3. Jide kii se akoigba

Igbelewon:-

 1. Ko awon eya gbolohun nipa ise won
 2. Salaye ni kukuru pelu apeere meji meji

Ise Asetilewa :-  Ko eya gbolohun wonyi si le ;

 1. A ti ri gbogbo won
 2. Ta ni o jale
 3. E dake jeje
 4. Ba mi toju re daadaa
 5. Olu ko wa ni ona.

ASA :-  Asa iranra-eni lowo II

Awon egbe iranra-eni lowo ode oni je eyi ti o ni ase ati atileyin ijoba ninu.  Die lara won ni yi ;

 1. Egbe Iranlowo :-  Iru egbe yii ni a ti n ri odomokunrin ati odomobinrin ni odugbo tabi ilu kan naa ti a o o si yan akikanju laarin egbe gege bii oloye.  Ni opo igba, egbe yii ni o n dagba pelu awon to da a sile ti yoo si di egbe agba ati egbe arugbo.

Ajosepo ti o dan moran maa n wa laarin awon omo egbe, won a maa dide si ohun inawo bii, igbeyewo, isomoloruko.  Egbe yii ba kan naa a maa gbon iya nu fun omo egbe, ebun lorisirisi ko lo n ka ti awon omo egbe maa n je latari ibasepo won pelu egbe.

 • Egbe oselu :-  A n da egbe yi sile lati fi se ilu, a fi n tun iluse.  Tokunrin tobinrin ni o n wa ninu egbe yii.  Egbe oselu ni a fi n tun ilu se lode-oni.

Pupo omo egbe lo n dibo si ipo asoju ninu eto ijoba sugbon wobia at onijekuje, onimotaara-eni nikan lo po ju ninu awon oloselu orile ede Naijiria.  Kaka ki won tun ilu se ni se ni won n ba ilu je si.

 • Egbe Agbe :-  Egbe yii lo n wa itesiwaju fun awon agbe ni orile ede Naijira.

Erongba egbe yii ni lati wa ounje ati awon nnkan ti a n lo n i ayika wa ni opo yanturu fun ilo gbogbo eniyan.  Ba kan naa, lati mu ki ise naa rorun fun awon to n se e.

A da egbe yii sile ki awon omo egbe le fi ohun sokan lati lepa ona ti won yoo fi mu erangba won se.  lode-oni, ijoba ti n ya awon egbe low lati fi se ise agbe, oogun igbinre (igbin ire) ati eyi ti yoo mu ki  ile loraa si ni ijoba n pese fun awon agbe latari egbe yii.

Awon Egbe Igba Lode Miiran Ni Wonyi;

Egbe alasowopo

Egbe ogboni

Egbe olowo

Egbe oloogun

Egbe alaanu abbl.

Igbelewon:

 1. Ko egbe iranra-eni low ode-oni marun-un
 2. Salaye meta père.

Ise Asetilewa :- mu okan père lara awon egbe iranra-eni lowo igbalode wonyii ki o si salaye lekun un rere

LITIRESO :-  Kika iwe litireso ti ijoba yan.

OSE KERIN

Akole Ise:-  Ede:-  Aroko asapejuwe

Aroko je ohun ti aro ti a si se akosile re.

Aroko asapejuwe ni aroko ti a fi n se apejuwe bi eniyan, nnkan tabi ayeye kan se ri gan-an.

Apeere ori oro aroko asapejuwe

 1. Ile iwe mi
 2. Oja ilu mi
 3. Ounje ti mo feran
 4. Ijamba oko kan ti o sele loju mi

Igbese Aroko Asapejuwe

 1. Yiyan ori oro
 2. Sise apejuwe ero le see se sinu iwe ni ipu afo (paragraph) kookan.

Igbelewon :-

 1. Kin ni aroko
 2. Fun aroko asapejuwe ni oriki
 3. Ko igbese kiko aroko asapejuwe

Ise Asetilewa :- ko aroko ti o kun fofo lori ori oro yii “Oja Ilu Mi”

ASA:- Oge SiseI

Oge sise je asa aso wiwo ati itoju ara lati irun ori titi de eekana ese.

Tokunrin tobinrin lo n soge ni ile Yoruba sugbon aarin awon obinrin ni o wopo ju si.

Oge Sise Lorisirisi

 1. Aso wiwo
 2. Ila kiko
 3. Osun kikun
 4. Laali lile
 5. Tiroo lile
 6. Eti lilu
 7. Itoju irun ori
 8. Iwe wiwe abbl.
 9. Ila kiko :-  Idi pataki ti awon Yoruba fi n ko ila oju ni aye atijo ni lait da ara won mo ati lati bukun ewa ara.

Orisi Ila Oju

 1. Abaja :-  Eyi ni ila meta tabi merin ti a fa nibuu lori ara won.  O wopo ni agbegbe oyo
 2. Pele :-  Eyi ni ila meta ooro ti a fa si ereke.  O wopo ni agbegbe ijebu, ekiti, ijesa, ila orangun ati eko
 3. Baamu :-  Eyi ni ila to dabuu ori imu wa si ereke apa osi.  Idile oba n i o maa n ko ila yii ni ilu ogbomoso
 4. Yagba :-  Eyi ni ila meta teere ti o pa enu po ni eba enu.  O je ila awon eya igbonuna ati yagba abbl.
 5. Osun Kikun :-  Eyi da bu atike lebulebu, o pupa foo.  Awon obinrin maa n kun si oju, apa, ese, ati ara won ki won le maa dan ni awo.  Abiyamo tooto maa n kun osun si ara omo tuntun bee ni iyawo tuntun maa n kun si egbegbe ese re lati bukun ewa re.
 6. Tiroo Lile :-  Eyi maa n bukun ewa oju obinrin ni penpe oju won.  Awon okunrin miran naa n kan un lati bukun ewa.
 7. Laali lile :-  Ile tapa ni awon elesin musulumi ti mu wa si ile yoruba
 8. Irun ori :-       Okunrin – (a) ori fifa  (b) Ori Gige

Obinrin –  (a) Irun kiko  (b) irun didi bii, suku, patewo, panumo, kolese, ipako elede, koroba abbl.

 • Aso wiwo :-  Yoruba gbagbo pe aso ni iyi eniyan.  Idi niyi ti won fi n so pe “bi a ti n rin ni aa ko ni”.  Orisiri aso asiko.
 • Aso Ise :-  Oniruru ise ti a n se ni o ni aso ise.  Awon agbe a maa wo ewu penpe ti ko ni apa ati sokoto kookun.  Ni kukuru, bi ise ba ti ri ni aso ti a fi n se won maa n ri.
 • Aso iwole/iyile :-  Eyi ni aso ti a nlo ninu ile.  Aso iyile awon obinrin ni tabi, tabi yeri ti awon okunrin ni gberi ati sokoto kookun
 • As imurode :-  Yoruba bo won ni « aso igba ni aa da fun igba ».   bi olodumare ba se ke eniyan to ni yoo se da aso po to
 • Aso imorode obinrin:-  iro, buba, gele, iborun tabi pele, yeri
 • Aso imurode okunrin:-  dandogo, agbada, sapara, gbariye, dansiki, buba ati jalaabu, sokoto sooro.

Igbelewon:-

 1. Fun oge sise ni oriki
 2. Ko ona oge sise marun-un ni ile yoruba
 3. Salaye ni kukuru

Ise Asetilewa :- ‘Aseju oge, ete ati abunkun ni o n mu dani’ Tu keke oro

LITIRESO :-  Kika iwe litireso ti ijoba yan.

OSE KARUN-UN

Akole Ise:-  Ede:-  Akanlo ede

Akanlo ede ni awon ijinle oro ti itumo won farasin.

                    Akanlo Ede lorisirisi

 1. Eleyo oro
 2. Akoni/Akin – Akoni kan kii sojo loju ogun (Akikanju eniyan)
 3. Otelemuye – Awon otelemuye ti mu awon odaran naa lanaa (olopa inu)
 4. Dobode – dobode kan lasan ni o , o o ti mo ewa lounje ajesun (omugo)
 5. Oro ise
 6. Gbaradi – mura
 7. Fewo – jale
 8. Topinpin – wadi oro finnifinni
 9. Yari – binu
 10. Apola oro
 11. Fi enu ko – soro odi si eni ti o ju ni lo ti o si le ba te ni je
 12. Fi iru jona/fi ori fo ile agbon – fifa oran tabi wahala si ori ara eni
 13. Fi aga gbaga – di je
 14. Gbe iku ta – mu itiju kuro
 15. Fi mu finle – se iwadi
 16. Erin iyangi – erin ti ko ti okan wa
 17. Fa omo yo – yege
 18. Gbe odomi/wo gau –  ko sinu wahala abbl.

Igbelewon:- 

 1. Kin ni akanlo ede
 2. Ko itumo akanlo ede wayi ni ijule:- topinpin

Fin enu ko

Fi mu finde

Gbe iku ta

Ise Asetilewa :- ko itumo ijinle akanlo ede wonyi :-

 1. Ba ni je afoju ewure
 2. Na papa bora
 3. Eja n bakan
 4. Te oju aje mole
 5. Fi eje sinu tuto funfun jade.

Asa : Oge Sise Ii

Awotele Obinrin

 1. Agbeko: Eyi ni aso olowo meji teere ti won n wo si abe buba
 2. Tobi/Sinmi: Eyi ni aso olokun ribiti ti won n wo si abe iro, o maa n gun de orukun
 3. Komu: Eyi ni aso olowo teere meji ti won n wo lati bo oyan

Awotele Okunrin

 1. Singileeti: Won maa n wo si abe aso
 2. Pata: Won n wo si isale sokoto

Akiyesi : Aso wiwo ni olori oge sise

Igbelewo : (i) ko awotele obinrin meta (ii) ko awotele okinrin meji pere

Ise-Asetilewa:

Ko aroko lori “Oge sise laaarin awon Yoruba ni aye atijo dara ju ti aye ode oni lo”

Litireso: Kika iwe litireso ti ijoba yan

OSE KEFA

Akole Ise: Ede-Sise Aayan Ogbufo

Ayan ogbufo ni ti tumo ede kan si ede miiran.

Aayan ogbufo ti wa lati odun pipe alufaa Samuel Ajayi Crowther ni eni ti o tumo iwe mimo bibeli ede oyibo si ede yoruba ni odun 1844-1856

Ilana ti tumo Ede

 1. A gbodo ni imo pipe lori ede ti a fe tumo
 2. Ba kan naa, a gbodo ni imo pipe lori ede ti a fe tumo re si

Orisi itumo

 1. Ojulowo itumo : Eyi ni ti tumo oro ni ikookan bi won se wa ninu ede ti a fe tumo si ede keji
 2. Itumo afarajora : Eyi ni ki a mu gbolohun oro inu ede ti a fe tumo ki a lo oro ti o bamu regi ninu ede ti a n tumo re si Ni kukuru, itumo afarajora ni fifi oye ede ti wa gbe itumo kale

Aayan ogbufo eleyo oro

 EDE GEE SI EDE YORUBA
 AudienceOn woran
 CompetitionIdije
 JokeApare
 OverlapWonu ara
 ResearchIwadii
 TransferIsinipo
 MotivateMoriya
 PatternBatani
 StageOri itage
 IdeaOye

Igbelewon: (i) kin ni aayan ogbufo (ii) ko ilana ti tumo ede kan si omiran meji (iii) orisi itumo ede meloo ni o wa? (iv) tunmo awon oro wonyi si ede Yoruba (a) Yes (b) Tale (d) Method

Ise Asetilewa: Tumo awon eyo oro ede geesi wonyi si ede Yoruba (i)Accident (ii)Boundary (iii)Yeletide (iv)Knowledge (v)Lack (vi)Race (vii)Seperation

Asa: Igbeyawo ibile

Asa Yoruba je okan lara awon asa to se pataki ni awujo Yoruba o je ase ti Olodumare fun awa eda lati maa bi si ki a si maa re si.

Yoruba bo won ni “bi omode ba to loko ni a n fun loko” Omokurin ni o maa n gbe iyawo ti a si n fomo obnirin foko ni ile Yoruba

Ilana asa igbeyawo ibile

 1. Eto ifoju sode: ohun akoko ti obi omokunrin to ti balaga yoo se ni fifi oju sode lati wa omobinrin ti o rewa fun omo won okunrin
 2. Alarina: Eyi ni eni ti yoo maa sotun sosin laaarin awon omokunrin ati omobinrin leyin ti a bati se iwadi idile ati iru ebi ti omobinrin naa ti wa
 3. Ijohan/isihun:- Ni geere ti omobinrin ba ti gba lati fe omokunrin ni a n pe ni ijohen.  Owo akoko ti omokunrin n fun omobinrin ni geere ti o ba ti gba lati fe e ni “owo ijohen”
 4. Itoro:-  Awon obi ati ebi omokunrin ni yoo lo si ile awon omobinrin lati lo toro re gege bi iyawo afesona fun omo won.
 5. Idana:-  Oniruuru ohun ti enu nje bii, igo oyin, ogoji isu, obi, orogbo, apo iyo kan, igo oti, aadun, eso loriisirisi aso iro meji, owo idana, abbl. Ni ebi omokunrin naa yoo ko lo si ile obi omobinrin ti won fe fi se aya fun omo won leyin naa won a mu ojo igbeyawo.
 6. Ipalemo:-  Eyi ni sisi eto lori bi ojo igbeyawo yoo se yori si ayo
 7. Igbeyawo :-  Ojo yii gan-an ni eto igbeyawo lekun-un rere sise si so yoo wa nile iyawo ati oko, iyawo yoo maa gba ebun lorisiirisi ati owo.  Ojo yii gan-an ni iyawo yoo fi ayo, orin ati ekun gba adura lodo awon obi re.

Igbelewon :-

 1. Ni kukuru salaye asa igbeyawo
 2. Ko ilena igbeyawo ibile ni sisentele

Ise astilewa :-  Nje loooto ni pe awon ilana asa igbeyawo ibile wonyii si fi ese mule ni ile Yoruba titi di oni ? salaye bi o se ye o si

LITIRESO :-  Kika iwe litireso ti ijoba yan.

OSE KEJE

AKOOLE ISE:-  Ede:-  SIse Aayan Ogbufo

Oye oro ti o wa ninu gbolohun ni a n se itumo kii se eyo oro nitori pe ehun gbolohun oro Yoruba yato si ti gbolohun oro geesi

Apeere ese ewi geesi si ede Yoruba;

Time was

When I could hardly sleep

For the noise

They made

All the girls

Had companions

An old woman never lacked

Strong and willing arms

To split her wood.

Ogbufo.

Asiko kan wa to je pe agbara kaka ni mo fi n ri oorun sun nitori pe won n pariwo.  Gbogbo awon omobinrin lo ni alabaarin, iya arugbo gan-an kii se alairi giripe eniyan ti o setan lati baa la igi re.

A o ri i daju pe ninu apeere yii, bi a ba ni ki a tele eto ilana ewi geesi ati itumo awon eyeo oro kookan n I sise-n-tele a ko ni le gbe itumo to ye kooro jade.

Igelewon:-  Tumo ede geesi won yi si ede Yoruba

 1. His body is cold as snow
 2. The room is hooter than fire

Ise asetilewa:-  se ogbufo ede geesi wonyi;

 1. Where are all the gories?
 2. We shall serve no master, king or slave
 3. Deceive yourself not, accept your fate
 4. The room is hotter than fire
 5. His body is cold as snow.

ASA:-  Asa igbeyawo ni ile Yoruba – Igbeyawo Ode Oni

A le pin igbeyawo ode oni si ona meta.  Awon niyi ;

 1. Igbeyawo soosi
 2. Igbeyawo mosalesi/yigi siso
 3. Igbeyawo kootu

IGBEYAWO SOOSI

Igbeyawo yii wopo laarin awon elesin kirisiti.  Alufaa ijo ni o maa n so okunrin ati obinrin po pelu Bibeli ti elerii lati inu ebi mejeeji yoo si fowo si iwe eri.  Inu soosi ni igbeyawo yii ti n waye.  Ko si aaye fun ikosile tabi ki okunrin ni ju aya kan lo ninu igbeyawo soosi.

IGBEYAWO MOSALASI/YIGI SISO

Eyi ni igbeyawo laarin okunrin ati obinrin ni mosalasi tabi ibudo miiran ki oko ati aya ba fe.  Aafaa ni yoo so okunrin ati obinrin po pelu oruka ife gege bii edidi ife.  Aaye wa fun oko lati fe iyawo miiran le iyawo tuntun ati pe won le fi ara won sile ti won ba ri i pe ife ko si ni aarin won mo.

IGBEYAWO KOOTU

Eyi ni isopo laarin okunrin ati obinrin ni kootu ijoba pelu ofin.  A tun le pe e ni igbeyawo alarede.  Adajo ile ejo ni yoo so okunrin ati obinrin po pelu ofin.  Oko ati iyawo ko ni eto lati fi ara won si le laise pe won jawe iko sile fun ara won ni abe ofin.

Igbelewon:-

 1. Ona meloo ni a le pin igbeyawo ode oni si
 2. Salaye igbeyawo ode oni lekun-un rere

Ise Asetilewa : Salaye Pataki alarinna ninu eto igbeyawo ni ile Yoruba

LITIRESO- Kika iwe litireso ti ijoba yan

OSE KEJO

Akole Ise:-  Ede – Onka ede Yoruba lati ookan de egba (1-2000)

Onka Yoruba je ona ti a n gba lati ka nnkan ni ona ti yoo rorun.

Nonba

1                      ookan

2                      Eeji

3                      eeta

4                      eerin

5                      aarun-un

6                      eefa

7                      eeje

8                      eejo

9                      eesan-an

10                    eewaa

20                    ogun

30                    ogbon

40                    ogoji

50                    aadota

60                    ogota

70                    aadorin

80                    ogorin

90                    aadorun-un

100                 ogorun-un

110                 aadofa

120                 ogofa

130                 aadoje

140                 ogoje

150                 aadojo

160                 ogojo

170                 aadosan-an

180                 ogosan-an

190                 aadowa (igba o din mewaa)

200                 igba

300                 oodunrun

400                 irinwo

600                 egbeta

800                 egberin                      

1000               egberun

1200               egbefa

1400               egboje

1600               egbejo

1800               egbesan

2000               egbewa (egbaa)

Igbelewa:- 

 1. Fun onka ni ori ki
 2. Ka onka lati ookan de egbaa

Ise Asetilewa : ko onka Yoruba lati igba de egbaa

ASA:-  Asa Igbeyawo

Eto Igbeyawo Soosi

 1. Baba iyawo yoo mu iyawo wo inu soosi
 2. Alufaa yoo gba toko-taya ni imoran bi won se le gbe igbe aye alaafia ninu Jesu
 3. Ikede:- Alufaa yoo bere lowo ijo boya a ri enikeni ti o ni idi kan ti ko fi ye ki a so toko-taya po ki o wi tabi ki o pa enu mo titi Jesu yoo fi de.
 4. Alufaa yoo sip e tokotaya siwaju lati so won po pelu eje pe iku nikan ni yoo ya won
 5. Alufa yoo  fun won ni oruka gege bi edidi igbeyawo
 6. Alufaa yoo fi won han gbogbo ijo gege bi oko ati aya
 7. Ifowo si iwe eri oko ati aya pelu awon ebi mejeeji pelu ijo ati ayo
 8. Leyin eyi ni gbogbo ijo yoo lo si yara igbalejo fun jije, mimu, bibu akara oyinbo, gbigba ebun igbeyawo lorisirisi pelu ijo ati ayo.

ETO IGBEYAWO MOSALASI/YIGI SISO

 1. Adura ibeere
 2. Aafaa yoo bere lowo obi oko ati aya boya won gba lati je ki awon omo won fe ara won
 3. Aafa yoo kewu bee ni yoo gba oko ati iyawo ni imoran lati gbe igbe aye alaafia gege bi loko laya
 4. Awon obi mejeeji yoo sadura fun awon omo won pelu owo adura
 5. Aafa yoo fi oruka so oko ati iyawo po gege bii edidi ife won
 6. Ba kan naa, aafa yoo se ifilo pe aaye wa fun oko lati fe iyawo miiran le iyawo to fe ati pe won le fi ara won sile ti won ba rii pe ko si ife mo laarin won.

ETO IGBEYAO KOOTU

 1. Okurin ati obinrin yoo koko lo fi oruko sile lodo akowe kootu
 2. Leyin eyi ni won a gbe ohun jije ati mimu bii, bisikiti eso lorisiri, oti elerindodo abbl, lo si kootu loju ti won ti da fun won.
 3. Adajo ile ejo yoo kede boya ariwisi wa si isopo awon mejeeji
 4. Ni ojo igbeyawo, oko, iyawo ati awon asoju won yoo lo si ile ejo lati bura gege bi esin won
 5. Oko, iyawo, awon ebi, asoju ati awon eleri meji yoo fi owo si iwe eri igbeyawo
 6. Ba kan naa, oko ati iywao yoo fi oruka si ara won lowo gege bii edidi ife
 7. Leyin eyi, akowe kootu yoo se ifilo pe oko ko le fe iyawo miiran laise pe o jawe ikosile fun iyawo re ni abe ofin.

Igbelewon:-  ko ilana igbeyawo ode oni ni sise n tele

Ise asetilewa:-  nje igbeyawo ibile dara ju igbeyawo ode oni lo bi? Tu keke oro

LITIRESO:-  Kika iwe litireso ti ijoba yan.

OSE KESAN-AN

ASA:- Asa oyun ninu (Itoju oyun ait omo bibi)

Ipo alailegbe ni awon yoruba fi omo si nitori won gbagbo pe laisi omo, idile ko lee gboro bee si ni itesiwaju ko le si ni awujo.

Awon ohun to le fa airi oyun obinrin

 1. Bi nnkan osu obinri ko ba dara tabi to ba n se segesege
 2. Asilo oogun tabi oyun sisee to ti se akoba fun ile omo
 3. Aisan inu gbigbona
 4. Aisan atosi tabi jerijeri olojo pipe lara oko
 5. Ti obinrin ba ya akiriboto tabi ti oko je akura.

Awon ami pe obinrin ti ni oyin ni wonyi ;

 1. Tuto sere-sere kiri ile
 2. Aya rin-rin tabi ki obinrin maa bi
 3. Ki obinrin maa too gbe ni gbogbo igba
 4. Ki o maa re obinrin lati inu wa.

Oniruru aajo ti won n se fun aboyun

 1. Oyun dide :-  Itoju aboyun bere ni kete ti won ba ti fi yesi pe oyun naa ti duro.  Oko tabi agba obinrin ile yoo mu alaboyun lo sodo anisegun agbebi tabi babalwo, onisegun yii yoo de oyun naa ki o maa ba wale tabi baje titi di akoko ti yoo fi bi omo naa.
 2. Sise orisi aseje fun aboyun :-  Awon aseje yii lo maa n dena aisan bii oyi oju, ori fifo, inu rirun, ooru inu abbl, ti yoo si mu ki omo naa maa dagba ninu ki o si le gbo daradara
 3. Wiwe ati mimu awon agbo igi :-  Eyi yoo fun aboyun ati omo inu re lokun.

Oniruuru Idarulekoo ti aon eleto iilara n se fun awon alaboyun lode-oui

 1. Lilo si ile iwosan fun ayewo to peye
 2. Gbigba abere ajesara lati le daan bo boo mo inu
 3. Jije awon ounje asara lore bu, ewa, eja, era, wara abbl.
 4. Mimu omi daradara
 5. Jije eso ati ewebe
 6. Sise ore idaraya ni asiko ti o wo
 7. Sise imototo ara ati ayika.

Igbelewon:-

 1. Ki ni awon ohun to le fa airi oyun obinrin
 2. Ko awon aimi ti o fihan pe obinrin ti ni oyun merin
 3. Ko oniruru aajo ti won ni se fun aboyun ni ile yoruba meta
 4. Lode oni oniruuru idanilekoo wo ni awo eleto ilara maa n se fun awon aboyun ?

Ise Asetilewa :-  se afiwe itoju oyun ti ibile ati ti ode oni

LITIRESO :-         

Itan oloro geere gege bi orisun itan isedale ati asa Yoruba.

ONA TI ITAN ATENUDENU GBA JE ORISUN ITAN ISEDALE ATI ASA YORUBA

 1. Itan fi ye wa pe omo iya ni ode ondo ati iwoye je.  Oba alaafin Ajuwon ti apele re n je ajaka ni baba won.  A gbo pe ibeji ni awon mejeeji omo oba si ni won.  Laye atijo apeere buruku ni  omo ibeji je ati pe pipa ni a maa n pa won ki won to dagba rara.  Sugbon baba won ko fe pa awon omo yii kia lo wi fun iyawo re ki o gbe won jinna rere si ilu ti won wa o si fun aya re ni opolopo owo, ounje, ohun eso ati erubinrin ati erukunrin.

Ilu ti iyawo ajaka tedo si ni ode ondo.

Itan fi ye wa pe okan ninu awon omo ibeji yii tedo si ode ondo ekeji si tedo si iwoye ni ago iwoye ni ile ijebu.  Akooni ati ode ni awon omo Ajaka.  Oruko oye awon ilu mejeji yii fi ajosepo han pe omo iya ni won oye oba ondo ni « osemawe », oye oba iwoye ni « ebumawe ».

 • Itan miran fi ye wa pe omo omo olofin oba ife ni igba kan ni owa ajaka.  Lara awon omo iya re ni orangun oba ila ati Alara oba ara.  Itan fi ye w ape oba olofin ko le riran daada mo ni gba ti o darugbo.  Ko da oju re mejeeji fo awon onisegun si ti gbin yanju lati woo san sugbon pabo lo jasi.  Omo omo re se ileri lati lo bu omi okun gege bii oogun iwosan fun olofin gege bi onisegun se so, iyalenu lo je pe ni geere ti o lo bu omi ji awon egbon re ti ko gbogbo ogun baba won patapata lai ku kan, okgun ko siri ohun ka pato fun omo omo re ayafi ida ajasegun re.

Omi okun ti owa bu yii ni a fi n pee ni « owa oboku » ba kan naa, ida Ajasegun ti olofin fun un lati maaja kiri ni a fi n pee ni « Ajaka »».  idi ni yi ti a fi n pe e ni « owa obokun Ajaka » titi di oni.  Ile ijeba ni osi fi se ibujoko

Igbelewo :-

 1. So itan isedale ilu ondo ati iwoye
 2. So itan isedale ilu ijesa

Ise Asetilewa:-  Ko aroko lori okan ninu awon akoni wonyi:-

 1. Ogunmola
 2. Sodeke
 3. Afonja

OSE KEWAA

AKOLE ISE:-  Ede:-  Aroko asotan oniroyin

Aruko oniroyin je mo itan tabi isele kan to sele ti a wa n royin re fun elemiran.

Iroyin bee le je isele atinuda alarako tabi ojumilose

AWON IGBESE AROKO

 1. Ori Oro :-  Ila akoko ni a n ko o si.

Apeere ori aroko oniroyin ni wonyi ;

 1. Iroyin odun osun osogbo ti mo wo
 2. Isomoloruko kan ti won se ni ile wa laipe yii
 3. Irinajo ojumito si ago olopaa
 4. Ere akonilekoo kan ti mo wo
 5. Ilapa eto:-  Aroko gbodo wa ni sise-n-tel ni ipin afo.
 6. Ifaara :-  eyi ni ipin afo to bere aroko ko gbodo gun ju
 7. Koko:-  eyi ni koko ti a fe soro le lori
 8. Ikadii :-  ikadii ni a o ti fi iho ti a ko si koko aroko wa han. So ki ni obe oge ni ikadii wa gbodo je
 9. Ede :-  Ojulowo ede yoruba ati ona ede to jiire ni a gbodo fi ko aroko wa ki a si yera fun lilo ede adugbo tabi eka ede.

Igelewon :-

 1. Kin ni aroko oniroyin
 2. Salaye igbese aroko oniroyin meta

Ise Asetilewa :-  ko aroko ti ko din ni 250 eyo  oro lori okan ninu aroko wonyi.  Lo ede yoruba ode oni ati ede iperi to jiire.

 1. Rogbodiyan akekoo ti o soju mi
 2. Ere akonilogbon kan ti mo wo
 3. Ijanba ina kan ti o sele ni oju re.

ASA:- ASA ISOMOLORUKO

Asa isomoloruko je ona ti a n gba fun omo tuntun ni oruko ti yoo maa je titi lai ni ile Yoruba.

Gbogbo ohun ti Olodumare da saye lo ni oruko.  Oniruuru ohun elo tabi eronja ni Yoruba si maa n lo nigba ikomojade.  Ojo kefa ni Yoruba n so omo loruko iba se omokunrin tabi omobinrin tabi ibeji.  Sugbon ni ibo miiran ni ile Yoruba, ojo kesan-an ni won n so omokunrin loruko, ojo keje ni ti obinrin, ti awon ibeji ni ojo kejo.

DIE LARA OHUN ELO ISOMOLORUKO NIYI;

OHUN ELO            IWURE

Obi                      bibi lobi n biku danu, bibi lobi ni baarun danu, obi a bi ibi aye re danu

Orogbo              orogbo maa n gbo saye o o gboo, wa a to, wa gbo kegekege, o koo ni gbo igbo iya

Oyin                   a kii foyin senu ka roju koko, oro bi oyin bi adun ko ni dagbere fun o ko ni je     koro laye

Oti                       oti kii ti, o ko ni ti laye bee ni oti kii te, o ko ni te

Epo pupa           epo ni iroju obe aye re a roju

Iyo                      iyo nii mu obe dun, iwo ni o maa mu un awon obi re dun

Atare                  ataare ki bimo tire laabo, fofo ni le ataare n kun.  Ile re a kun fomo

Igbelewon :-

 1. Fun asa isomoloruko loriki
 2. Ko ohun elo ismomoloruko maru-un ki o si fi se iwure

Ise Asetilewa :- N je lilo awon ohun elo isomoloruko ibile wonyii ni ile yoruba si fi ese mule bi ?

LITIRESO :- Alo Apomo ati Apagbe

Alo ni oro elo ti o je afiwe ti o si maa n so nnkan ti ko se e se nigba miiran.

Alo maa n so nnkan ti ko ni eemi di ohun elemii.

ORISI ALO

 1. Alo apamo
 2. Alo apagbe/onitan

ALO APAMO

Eyi ni alo ibeere ait idahun.

Apeere ;

Ibeere :-  Awon agba marun-un sin olu-ife lo si ogun, agba marun-un pada wale, olu-ife ko wale.

Idahun :-  Okele eba ni olu-ife, ika owo marun-un ni agba marun-un

Akiyesi :-  Ohun ti ko ni eemi ni aso di ohun elemii

AAFAANI ALO APAMO

 1. O wa fun itaniji
 2. O n da ni le koo
 3.  O wa fun idaraya
 4. O n ko omode nipa ilo ede
 5. O n je ki omode ronu jinle
 6. O n je ki omode ni igboya lati le soro ni awujo

ALEEBU

 1. O n je ki omode yo ise ile sile
 2. O n ko omode ni isokuso
 3. Ki n je ki omode tete su lale

ALO APAGBE/ONITAN

Alo apagbe ni alo orin ati ijo.

Itan aroso laisan ni.

ANFAANI ALO APAGBE

 1. O n ko ni lekoo
 2. O n bu neu ate lu iwa ibaje bii ole jija, okanjua sise, iro pipa, eke sise, igberaga abbl.

KOKO INU ALO ONITAN

 1. Itan ti o n ko ni lekoo
 2. Itan ijapa
 3. Itan ti o n os idi abajo

Igbelewon :- 

 1. Kin ni alo
 2. Orisi alo meloo ni o wa
 3. Salaye orisirisi alo won yi lekun-un rere

Ise Asetilewa :-  pa alo apagbe kan ti o mu ogbon dani

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button